Ìjọba-àpapọ̀ sọ Èkó di ìpínlẹ̀ ni àádọ́ta ọdún sẹhin. Èkó jẹ́ olú ilú fún gbogbo orilẹ̀ èdè Nigeria tẹ́lẹ̀ ki wọn tó gbe lọ si Abuja. Ìpínlẹ̀ Èkó jẹ ikan ninú ipinle mẹ́fà Yorùbá.
Yorùbá ni “Èkó gba olè, ó gba ọlẹ”, ọ̀rọ̀ yi jẹ wi pé kò si irú ẹni ti ko si ni ìpínlẹ̀ Èkó nitori Èkó gba olówó, ó si gba aláini àti wi pé iṣẹ́ pọ̀ ni Èkó ju gbogbo ìpínlẹ̀ yoku lo. Kò si ẹ̀yà tàbi ẹ̀sìn Nigeria ti kò si ni Èkó. Nitori èyi èrò pọ̀ jù ilẹ̀ lọ nitori omi ló yi Èkó ká.
Àwọn Gómìnà ti ó ti jẹ lati ìgbà ti wọn ti dá ìpínlẹ̀ Èkó silẹ̀ ni wọnyi:
Gómìnà Kini – Ọ̀gágun Àgbà Mobọ́lájí Johnson – Gómìnà fún ọdún mẹjọ – àádọ́ta ọdún si ọdún méjìlélógójì sẹhin
Gómìnà Keji – Gómìnà Ori Omi Adékúnlé Lawal – Gómìnà fún ọdún méjilá – ọdún mejilélógójì titi di ogóji ọdún sẹhin
Gómìnà Kẹta – Ọ̀gágun Ori Omi Ndubuisi Kanu – Gómìnà fún ọdún kan – ogójì ọdún titi di ọdún mọ́kàndinlógójì sẹhin
Gómìnà kẹrin – Ọ̀gágun Ori Omi Ebitu Ukiwe – Gómìnà fún ọdún kan – ọdún mọ́kàndinlógóji titi di ọdún méjidinlógóji sẹhin
Gómìnà Karun – Alhaji Lateef Jakande – Gómìnà Ìjọba Alágbádá fún ọdún mẹrin – lati ọdú́n mejidinlogoji titi di ọdún merinlelogbon sẹhin
Gómìnà Kẹfà – Ọ̀gágun Òfúrufú – Gbọ́láhàn Múdàṣírù – Gómìnà fún ọdún meji – ọdú́n mẹ́tàlélogbon di ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n
Gómìnà Keje – Ọ̀gá Adarioko Ojúomi Mike Akhigbe – Gómìnà fún ọdún meji – ọdú́n mọ́kànlélọ́gbọ̀n di ọdún mọ́kàndinlọ́gbọ̀n sẹhin
Gómìnà Kẹjọ – Ọ̀gágun Àgbà Rájí Ràsákì – Gómìnà fún ọdún mẹrin – ọdú́n mọ́kàndinlọgbọn di ọdú́n márùndinlọ́gbọ́n sẹhin
Gómìnà Kẹsan – Ọ̀gá Michael Ọ̀tẹ́dọlá – Gómìnà fún ọdún kan àti oṣù mẹwa – ọdú́n márùndinlọ́gbọ́n titi di ọdún mẹ́rinlélógún sẹhin
Gómìnà Kẹwa – Ọ̀gágun Ọlágúnsóyè Oyinlọlá – Gómìnà fún ọdún meta – ọdún mẹ́rinlélógún di ọdún mọ́kànlélógún sẹhin
Gómìnà Kọkànlá – Ọ̀gágun Mohammed Buba Marwa – Gómìnà fún ọdún mẹ́ta – ọdún mọ́kànlélógún di ọdún mejidinlógún sẹhin.
Gómìnà Kejilá – Ọ̀gbẹ́ni Bọla Ahmed Tinubu – Gómìnà Ìjọba Alágbádá fún ọdún mẹjọ – ọdún mejidinlógún titi di ọdún mẹwa sẹhin
Gómìnà Kẹtàlá – Ọ̀gbẹ́ni Babátúndé Rájí Fáṣọlá – Gómìnà Ìjọba Alágbádá fún ọdún mẹ́jọ – ọdún mẹwa titi di ọdún meji sẹhin
Gómìnà Kẹrinlá – Ọ̀gbẹ́ni Akínwùnmí Ambọde – Gómìnà lọ́wọ́lọ́wọ́ lati ọdún meji titi di òni
Yàtọ̀ si ìgbà Ìjọba Ológun, Èkó gbádùn ìdúróṣinṣin ni àsìkò Ìjọba Alágbádá tàbi Ìjọba Tiwantiwa lati ọdún kẹtàdínlógún sẹhin. Eyi jẹ ki ipinle Èkó mókè ju gbogbo ìpínlẹ̀ yókù lọ.
English Version
Continue Reading after the page break