Home / Art / Àṣà Oòduà / Iwulo Ati Anfaani Ti Orí Nse Ninu Igbesi Ayé Omo Eda Eniyan
Ori
Iyalorisa Omitonade Ifawemimo‎

Iwulo Ati Anfaani Ti Orí Nse Ninu Igbesi Ayé Omo Eda Eniyan

Ekaaro eyin eniyan mi, aku ise ana o, a sin tun ku imura toni, mose ni iwure laaro yi wipe Eledumare ninu aanu re koni jeki ire oni yi fiwa sile Àse.
Idanileko mi toni da lori orí wa, opolopo ni ko mo iwulo ati anfaani ti orí nse ninu igbesi ayé omo eda eniyan, orí je pataki ninu gbogbo eya ara, koda mo fe le sope orí ni gbogbo nkan ile ayé yi, kosi nkankan ti a le se laifi imo orí si, koda ki o je babalawo, onisegun, ologboni, olorisa abi eyikeyi yowu ki o je ti o ba fi ti orí re se lasan ni o nse, koda àwon orisa re koni fohun daradara fun o, orí lo siwaju ayé ki a to tele, fun idi eyi e jeki a maa toju orí wa daradara, orí koni binu siwa o Àse.
E jeki a gbo nkan ti odù ifá mimo obara bubu so nipa orí.

Ifá náà ki bayi wípé:
Òbàràbogbè tomo awo se babalawo orí difa fun orí lojo ti orí ntorun bo wa saye won ni ki orí karaale ebo ni ki o wa se nitori ki o baa le kogo ile ayé ja, obi meji…….ati igba ewe ayajo ifá, orí kabomora orí rúbo won se sise ifá fun, bi orí se di nla niyen to si kogo ile ayé ja, orí bere sini njo o nyo o nyin babalawo àwon babalawo nyin ifá, ifá nyin Eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifá wa bami ni jebutu ire nje jebutu ire ni a nbawo lese obarisa.
Orí wa fiyere ohun bonu wípé:
Òrò mi ko kan egúngún o
Òrò mi ko kan aláwoo
Sebi orí mi lòrò mi kan oo.
Eyin eniyan mi, mose ni iwure laaro yi wipe orí wa yio se rere laye, orí wa koni gba àbòdè fun ise rere ati ilosiwaju wa nile ayé, orí wa yio ko opolopo ire ojó oni funwa o ako ni se lasan lase Eledumare o Àaaase.
ÀBORÚ ÀBOYÈ OOO.

English Version

Continue reading after the page break

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti