Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a si tun ku imura toni, mo gbaladura laaro yi wipe gbogbo awon ota ti won ba sope ako ni se rere yio di gige kuro lori ile alaaye loni o ase.
Laaro yi mo maa fi odu mimo ejioore se iwure fun wa latari bi a se mo ise aburu ti awon elenini nse lati ma fe jeki eniyan se rere ati saseyori nile aye, c ko sibiti elenini ko si laye yi, o wa nile ti a ngbe o wa ladugbo ati ibi ise wa, sugbon eyikeyi ninu won to ba sope oun koni jawo leyin wa yio di eni akolebo loni.
Ifa naa ki bayi wipe:
Igba awodi nla ni nfiye apa se ilu legan a difa fun Atalanpako eyiti nse elenini baranipetu seni Atalanpako maa nse ènìní baranipetu nkakiri ibi gbogbo, won ni ki baranipetu karaale ebo ni ki o wa se nitori ki o baa le segun elenini re, obi meji, igiripa obuko, ida olominimini, abe ati igba ewe ayajo ifa baranipetu kabomora o rubo won se sise ifa fun, nibiti Atalanpako ti gbe nse enini baranipetu ibe ni abe ifa ti koó lori ti ida olominimini si ti ni lorun bi atalanpako se ku niyen o ti aye ifa wa dofe moore, ijo ni baranipetu njo ayo lo nyo o nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nbawo lese obarisa.
AKOSE IFA RE: ewe ida olominimini, ewe àró, ewe arogbo, ewe uda, ewe udi ao gun papo mose ao fi eje obuko naa po lehin ti abati fi bo esu tan, ao gbaye ifa naa si ao ko sinu igba olomori ao fi obe oloju meji gun lori ao maa fi obe yen bu ose yi sori kanhinkanhin iwe, hmmn! Ifa isegun elenini todaju ni.
Eyin eniyan mi, mo se ni iwure laaro yi wipe gbogbo awon elenini aye wa ni ifa yio fi ida re be lori, gbogbo awon alatako nibi ise wa tabi ladugbo ni won yio ku iku itiju, ao segun ota ao si reyin odì lagbara Orunmila mimo alagbawi wa aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.
ENGLISH VERSION:
Continue after the page break