Home / Art / Àṣà Oòduà / Iwure: Odu Okanransode

Iwure: Odu Okanransode

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Abu ise ana o a si tun ki orire iwonu ose tuntun, ose yi yio san wa si ire gbogbo ako ni to ona iparun lose yi o ase.
Laaro yi mo maa fi odu mimo okanransode se iwure fun wa fun wiwo inu ose tuntun.
Ifa naa ki bayi wipe:
Orunmila ni ki olokanran sode
Emi naa moni ki olokanran sode
Orunmila ni bi Omo eku bati ji bi ko ba sode o maa sagbo ìrá
Orunmila ni ki olokanran sode
Moni ki olokanran sode
Oni bi Omo eja bati ji bi ko ba sode o maa sagbo ira
Orunmila tuni ki olokanran sode
Moni ki olokanran sode
Oni bi Omo eniyan naa bati ji bi ko ba sode o maa sagbo ira
Mo wani Orunmila kilode to fi nfo bi ede bi eyo
Orunmila loun ko fo bi ede bi eyo oni akapo toun ti won da oun ifa fun ni oun nba soro wipe ti o bati ji laaro ki o maa fi opele sode nitori ki o ma baa sagbo ira ki o ba le mo ona to maa to.
Eyin eniyan mi, mo se ni iwure laaro yi wipe ako ni sagbo Ira o, ako ni tona iparun, gbogbo wahala wa lose yi koni jasi asan lase eledumare aaaase.
ABORU ABOYE OOO.

 

 

ENGLISH VERSION:
Continue after the page break

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

masoyinbo

#Masoyinbo Episode Fifty-One with ‪@yemieleshoboodanuru589‬ #Yoruba #learnyoruba #yorubaculture