Home / Art / Àṣà Oòduà / Iyanu ti sele nipa awon omo Babington Ikorodu ti won jigbe

Iyanu ti sele nipa awon omo Babington Ikorodu ti won jigbe

Ni ojo Aje to koja yii (29/02/15) ni awon ajinigbe kan yawo ileewe Babington Macaulay ‎Junior Seminary School to kale si agbegbe Ikorodu nipinle Eko ti won si ji awon omo obirin akekoo meta salo raurau.

Gege bi alaye ti oga agba ileewe naa, Ven Olaoluwa Adeyemi, se, o ni koto giriwo kan ni awon onisebi naa gbewole leyin ogba ileewe naa. Leyin ti won wole ni won bere si ni tabon tau-tau soke ti ina si n fo yo lenu ibon won bi igba ti Sango olukoso ba n binu. “Orisii ibon igbalode to wa lowo awon amokunseka naa lagbara pupo eleyii ti ko fun awon osise alaabo ileewe wa ni anfaani lati le doju ija ko won. Ologini foju jo amotekun ni, nnkan ju nnkan lo,” ogbeni Adeyemi se alaye naa bee.

Lara iwadii ti OLAYEMI ONIROYIN kojo lojo Isegun (01/03/16) ni wi pe, awon ajinigbe naa ti n beere ogorun milionu (N100m) lori omo kookan eleyii ti won tun pada din owo naa si ogun milionu (N20m). Okan ninu awon akoroyin wa gbiyanju lati ba okan ninu awon omo tabi oluko ileewe naa soro lojo keji isele naa sugbon awon alase ileewe naa ti paalase fun won lati ma dahun ibeere awon oniroyin kankan.

Ni ojo Wesde (02/03/16), Igbakeji gomina ipinle Eko to tun je komisanna fun eto eko, Arabirin Idiat Oluranti Adebule, se abewo si ileewe naa lati ba won kedun isele to waye naa. Bakan naa lo tun fi da won loju wi pe, ijoba yoo lo gbogbo agbara re lati gba awon omo naa pada wale.

Oludasile ileewe naa, Dr Michael Fape, ko sai dupe lowo ijoba ipinle Eko pelu bi awon osise alaabo ipinle naa se dide ni kanmonkobo nikete ti won fi isele naa to won leti. Gbogbo agbegbe ileewe naa si ni awon osise alaabo gunle si bayii lati daabo bo emi ati dukia.

Iru isele to jo iru eleyii ni eyi to sele ni oru ojo kerinla si ojo keedogun osu kerin odun 2014, nibi ti awon omobirin orinlugba o din merin (276) ti gbe di ohun awati ni Chibok. Bi o tile je wi pe lati igba naa ni awon omo ologun ile wa ti n ja raburabu lati ri awon omo naa ko wa le pada, sibesibe, ori igbiyanju naa ni ijoba apapo wa.

Wayio, komisanna fun etigbo ati agbekale ilana fun ipinle eko, Steve Ayorinde, kede laaro oni ojo Sande (7/03/16) wi pe awon omo naa ti di gbigba pade wale latari iranwo awon agbofinro ilu Eko

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

masoyinbo

#Masoyinbo Episode Seventy-three: Exciting Game Show Teaching Yoruba language and Culture