Home / Art / Àṣà Oòduà / KÍ LÓ BÀJẸ́ LÉDÈ WA

KÍ LÓ BÀJẸ́ LÉDÈ WA

Ẹ jẹ́ kí a tibi pẹlẹbẹ mú ọ̀lẹ̀lẹ̀ jẹ.
N jẹ́ fífi gẹ̀ẹ́sì kọ́ni lédè Yorùbá le múni yege dáada nínú ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá bí?
Gẹ́gẹ́ bíi òwe gẹ̀ẹ́sì kan tí ó wí pé, “the best way to understand a language is by speaking it”
Ọ̀NA KAN GBÒÓGÌ TÍ A FI LE GBỌ́ ÈDÈ KAN NÁÀ NI KÍ Á MA SỌÓ.
bi ko ba jẹ bẹ̀, àwọn àbùjẹ-ǹ-jẹkù tí ń bẹ nínú èdè gẹ̀ẹ́sì yóò ran Yorùbá náà. Bíi àpẹẹrẹ
Ìró èdè gẹ̀ẹ́sì ju iye álúfábẹ̀ẹ̀tì tí ó ní lọ.
Álúfábẹ̀ẹ̀tì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lè ní ìró kan soso nínú èdè gẹ̀ẹ́sì.
Oral English
yóò se àkóbá fún mímọ ìró èdè àti àmì ń lò nínú èdè Yorùbá.
Àwọn òfin gírámà èdè gẹ̀ẹ́sì yàtọ̀ gédéńgbé sí ti èdè Yorùbá.
Njẹ̀ bí a bá ń fi ìtọ̀ táńbà sé ìdí le mọ́ bí ?
Ìgbẹ́ ò ní tán nídìí.
Bí òórùn ìgbẹ́ bá kúrò lára ẹni, ìtọ̀ ń ḱọ?
Ẹni bá ní ànfànì láti gbọ́ èdè lárúbáwá ọ̀rọ̀ yí le yé wọn dáada.
Wàláì tàlàì a kò lè fi èdè míràn ḱọ́ Yorùbá ju èdè Yorùbá náà lọ.
Ẹ wo ilẹ̀ chaina, ilẹ̀ korea, àti àwọn ilè lárúbáwa, wọ́n kìí kọ̀ gẹ̀ẹ́sì médè wọn, ọ̀tọ̀ lórìn ni wọ́n fií ń se, bí gẹ̀ẹ́sì bá wù wọ́n gbó wọn yó sẹ̀sẹ̀ lọ kọ́ọ ni.
N jẹ́ bí ó bá jẹ́ àwọn ìwé kíkà ìmọ̀ tí ó kù wà ní kíkọ lédè Yorùbá ni, òkèlè Yorùbá kò bá dùn ní kòlọ́bẹ̀,
Bí a bá fi Yorùbá kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ, kòní sí wàhálà lórí lílo àkọtó èdè.
Bí èdè Yorù̀bá bá yé wa dáada a ó mọ àgbékà ọ̀rọ̀, èsì tí ó tọ́ àti bí ọ̀rọ̀ se wúwo tó.
“Bí ẹyẹ bá se fò ni kí á s’ọ̀kò rẹ.̀”
Bí a bá ń sọ̀rọ̀ ẹ jẹ́ kí á làdí ẹ̀ wò, kí a má joyè eléǹpe àkọ́kọ́ tó ní igbá wúwo ju àwo lọ, n ò pé kí a máà kọ́ èdè gẹ̀ẹ́sì, sùgbọ́n ẹ jẹ́ kí á gbọ́lá fún èdè wa,
Ẹ fi tó onílé létí, ẹ sọ f’álejò kó mọ̀.

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

masoyinbo

#Masoyinbo Episode Fifty-One with ‪@yemieleshoboodanuru589‬ #Yoruba #learnyoruba #yorubaculture