Àrídájú ti so wípé…
1. Àwon ènìyàn kan wà tí won ń lo orúko àti ipò Aláàfin láti fi lu àwon tí kò mò nípa Àsà yorùba ní jìbìtì ní ìlú òyìnbó.
2. Àwon babaláwo tí ó wà lábé ilé-ifá Ìjo ifá Àdìmúlà. Wón ń gbá àwon ènìyàn lórí èro ayélujàra (internet) nípa fífún won ni oyè orísirísi láì fi tó Aláàfin létí.
3. Aláàfin Oba Adeyemi, ti ń lo òfin láti ri wípé àwon afurasí oníjìbìtì wònyí San owó ìtanràn pé won fi Àsà yorùba wólè ní gbogbo àgbáyé.
4. Ààfin ti bèèrè gbàgede fún gbogbo elésìn àbáláyé láàrin ìlú kí won fi orúko sílè lábé egbé tí a mò sí Àsà òrìsà láti ri wípé wón wà ní ìbámu pèlú ìse onísèse àti láti kápá ìwà jìbìtì.
5. Orúko àwon afurasí wòn yí ni :Faniyi Awoniran Omoyemi, Ojelabi Okewole, Faleye Ikusaanu, Famuwagun Oloyede, Ifayemi Olaniyan, Ifakorede Ifaloseyi, Ifadotun Fatoki, Oyasogo Ifakorede, ifasooto Ifawumi Adeyemo, Awoniran Awotunde, Awoniran Ifamuyiwa àti béè lo.
6. Ikusaanu Faleye, Fasola Olaniyan àti Olaniyan Awoyemi nìkan ni ó ti Fara hàn ní ilé ejó ní ìyágànku Ibadan tí ó sì kun àwon tí ó pò.
7. Èsè mérin òtòtò ni a ti kà sí won lésè Èsè òdaràn, ìfirawé, Ayédèrú àti ìwà tí ó le mú ìpalára wá fún àláfíà ìlú.
8. Abánirojó, Fasola Sunday, sàlàyé wípé olùjéjó àti àwon tí ó ń se àfarawé Aláàfin fi oyè fún ènìyàn wípé kòsí oyè kankan tí ó ńlá jé Oba ifá ti gúúsù America (south America) lórí àtòhúnrìwá kankan.
9. Àwon olùjéjó se ayédèrú ìwé-èrí oyè náà tí won sì fi irú rè fún Franciva Leoa Nobres tí wón so ní Ifatoowo Adebayo :Dasiel Guerra, Awotunde Ajisola : àti Jose Lara tí won so ni Ifakayode Falade.
10. Àwon tí a fi èsùn kan wí àwíjàre pé àwon kò jèbi èsùn tí a fi kàn wón tí ó sì jé wípé Adájó AA. Adebisi sì fún won ní béèlì egbèrún lónà ogóòrun (#100,000) tí àrídájú isé sì wà, wón sún ejó nà lo sí ojó ketàdínlógún osù kefà (July 17).
11. Olúwo ti òyó Aláàfin, Ifatoki Ojo fi àrídájú lélè wípé babaláwo kankan kò ní àse láti fi enikéni je oyè láìní owó Aláàfin nínú
English Version
Continue after the page break