Ó ju ẹnu Malami lọ láti ní ètò náà kò bófin mu
Kí ojú má ríbi, gbogbo ara lòògùn rẹ̀, èyí ló mú kí Gómìnà ipinlẹ Ọyọ, Ṣèyí Mákindé sáré tètè gba ìlú Abẹokuta lọ, láti lọ ṣèpàdé pọ̀ pẹ̀lú Olóyè Olusẹgun Ọbasanjọ.
Gẹ́gẹ́ bi ìwé iroyin kan ti wi, abẹwo Seyi Makinde naa ko sẹyin bi ijọba apapọ se ni agbekalẹ eto alaabo Amotekun ko ba ofin ilẹ wa ọdun 1999 mu.
Déédé aago méjì kọjá Ìṣẹ́jú díẹ̀ ni Mákindé gúnlẹ sí ọgbà Ilé iyawe-kawe Ọbasanjọ tó wà nílùú Abẹokuta, tí àwọn méjéèjì sì jọ se ipade bonkẹlẹ.
Gómìnà Mákindé, ẹni tí Sẹ́nétọ̀ Hosea Ayoola Agboola àti olùdámọ̀ràn rẹ̀ fétò ààbò, Fatai Owoseeni kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú rẹ̀, jáde síta lẹ́yìn ìpàdé náà ní aago mẹ́rin ààbọ̀.
Nígbà tó ń báwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé náà, Mákindé ní Ìjọba àpapọ̀ kò lágbàra láti kéde pé Ìkọ Àmọ̀tẹ́kùn” kò bófin mu.
“Ní irú orílẹ̀èdè táa wà yìí, èmi kò rò pé ó yẹ kí irú agbẹjọ́rò àgbà nílẹ̀ wa ṣàdédé dìde, máa dá òfin se lọ́wọ́ ara rẹ̀’
“Kìí se ojú òpó ìkànsíraẹni lórí ayélujára ni èèyàn ti ń se ìjọba, ìhà tí màá sì kọ sí ohun tí Malami sọ kò bá yàtọ̀ tó bá jẹ́ pé ó kọ ìwé sí wa lórí ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ orí ayélujára nìkan ni mo ti ń ka ìròyìn ohun tó sọ”
Mákindé fikún pé ojúṣe agbẹjọ́rò àgbà nílẹ̀ wa ni láti gba Ààrẹ nímọ̀ràn lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó níí se pẹ̀lú òfin, àmọ́ èmi kò mọ òfin tó fún Malami lágbára láti sọ irú ohun tó kéde yii.
Fẹ́mi Akínṣọlá