Ìtàn fi yé wa wi pé Yorùbá ka ọ̀rọ̀ obinrin si ni àṣà Yorùbá bi ó ti ẹ jẹ wi pé obinrin ki jẹ Ọba nitori ni àṣà ilú, ọkunrin ló njẹ olóri. Obinrin kò pọ̀ ni ipò agbára. Àwọn ipò obinrin ni ‘Ìyáálé’, eyi jẹ́ iyàwó àgbà tàbi iyàwó àkọ́fẹ́ ninú ẹbí, pàtàki ni ilé o ni iyàwó púpọ̀ ṣùgbọ́n ọkùnrin ni ‘olóri ẹbí’. Ipò obinrin kò pin si idi àdìrò àti inú ilé yókù gẹ́gẹ́ bi Olóri Òṣèlú Nigeria, Muhammadu Buhari ti sọ.
Obinrin Yorùbá ti ni àyè lati ṣe iṣẹ́ ti pẹ́, bi ó ti ẹ̀ jẹ́ wi pé àwọn iṣẹ́ obinrin bi oúnjẹ ṣí ṣe, ẹní hí hun, aṣọ hí hun, aró ṣi ṣe, òwú gbi gbọ̀n, ọjà ti tà (ẹ̀kọ́ ọrọ̀ ajé díẹ̀), oúnjẹ sí sè àti itọ́jú ẹbi ni obinrin nṣe. Àwọn ọkùnrin nṣe iṣẹ́ agbára bi iṣẹ́ ọdẹ, alágbẹ̀dẹ, àgbẹ̀ tàbi iṣẹ́ oko (iṣẹ́ fún ji jẹ àti mimu ẹbí). Obinrin ni ògúná gbongbo ni oníṣòwò òkèèrè, eyi jẹ ki obinrin lè ni ọrọ̀ àti lati lè gba oyè ‘Ìyálóde’. Fún àpẹrẹ, àwọn Ìyálóde ni ó njẹ Olóri ọjà ni gbogo ilẹ̀ Yorùbá àti alá-bójútó fún ọ̀rọ̀ obinrin.
Gẹ́gẹ́ bi àṣà ibilẹ̀ Yorùbá, àwọn ọkùnrin gbà ki iyàwó wọn ṣe iṣẹ́ lati ran ẹbí lọ́wọ́, eyi lè jẹ́ nitori àwọn ọkùnrin ni iyàwó púpọ̀, nitori èyi, kò nira bi iyàwó kan tàbi méji bá lọ ṣòwò ni òkèèrè, àwọn iyàwó yókù yio bójú tó ilé. Àṣà òkè-òkun fi fẹ́ iyàwó kan àti ẹ̀sìn òkèère ti Yorùbá gbà ló sọ àdìrò di ipò fún obinrin àti “Alá-bọ́dó, Ìyàwóilé tàbi Oníṣẹ́-ilé” ti ó di iṣẹ́ obinrin. Obinrin ayé òde òní kàwé, ṣùgbọ́n bi wọn kò ti ẹ kàwé, gbogbo ẹni ti ó bá ni làákàyè fún àṣà, kò gbọdọ̀ já obinrin si ipò kankan ni ilé nitori obinrin ló ni gbogbo ilé.
English Version:
Continue reading after the Page break