Home / Art / Àṣà Oòduà / Odo Iwoyi – 2
yoruba

Odo Iwoyi – 2

Mo ki gbogbo Omo Yoruba Atata pata nile-loko ati leyin odi wipe a ku dede asiko yi, mo si ki awa ololufe eto Odo Iwoyi wipe e ku abo sori eto wa, eto yin, eto Odo Iwoyi ti ose yi. E wa nkan f’idi le abi ki e f’idi le nkan ki a jo gbadun ara wa bii ti ateyin wa. Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon ololufe eto yi ni a o maa Ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won nimoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO:-

 

“Olootu mo ki yin pupo fun ise takuntakun ti e n se lori eto yi, Eledua yoo San yin lesan ire o. Beeni mo ki gbogbo awa ti a ndasi eto yi wipe, a ku atunse, Eledua yoo tun ile ati ona enikookan wa se o. Ase

Olootu e jowo oro kan ni nbami lokan je, ti ko si fe yemi mo, eyi ti mo nilo amoran awon ojogbon eniyan lori re. Eni odun mokandinlogbon ni mi bayi. Isoro kansoso ti mo ni laye ni wipe lati igba ti mo ti balaga nko ri odokunrin kan ti o konu ife si mi ri. Oro na wa je kayefi fun mi, Koda mo ti gbadura gbaawe lori oro yi, sugbon nko ri ayipada, beeni mo rewa lobinrin ti nko si ni alebu kokan lara, eyi gan ni oro yi fi je iyalenu fun mi. Looto kii se wipe okunrin kii denu ife ko mi o, sugbon isoro ibe ni wipe, awon okunrin ti won ti laya nile koda awon miran ti ni meji beeni won yoo si maa da mi laamu wipe, awon yoo fe mi dandan ni.

 

Ohun ti o jomi loju julo ni wipe lati ile eko girama ni isoro yi ti bere, ipele ikarun ni mo wa ni odun yen loun ti oluko mi kan ti o ti laya meji nile bere si ndami laamu. Ohun ti o semi ni kayefi ni akoko yen loun ni wipe pelu gbogbo bi mo se n yakayaka okunrin yi ko deyin leyin mi, oro yi le debi wipe mo so fun awon obi mi wipe ti won ko ba paro ile eko mi, nko ni Ka iwe mo, sugbon o se mi ni kayefi wipe nkan kanna ni mo dojuko ni ile eko miran ti mo pada si, beeni o si tesiwaju ti mo fi wo ifasiti, koda o to akoko kan ti mo ma n fi ogbon ti ara mi si awon odokunrin lorun sugbon opo won ni ko wo ibi ti mo wa, awon ti yoo ba si wo ibi ti mo wa yoo kan se mi bi o ti wu won laarin osu melo kan ti won yoo si pami ti ni. Niwon igba ti o kuku je wipe emi ni mo gbe ara mi lo ba won.

 

Isoro yi tesiwaju titi mo fi pari eko ifasiti ti mo si bere ise, ni bayi arakunrin kan ni mo pade ni odun ti o koja, oga ile ise kan ni alagba yi, ore ni arakunrin yi ati oga ile ise ti mo ti n sise, alagba yi denu ife ko mi, ti o si se ileri lati fimi se aya, gege bi ojo ori alagba yi, mo bi won ni akoko na wipe, pelu ojo Ori yin yi ti e si je omo Yoruba se rara ni e koi tii ni iyawo ni? Alagba yi si da mi lohun wipe looto awon ti ni iyawo ri ti awon si ti bi omo meji sugbon ni bayi awon ko si pelu obinrin kokan. Opolopo ibeere miran ni mo bi Alagba yi, ti won si da mi lohun leseese. Mo tesiwaju pelu Ogbeni yi, leyin bi osu mejo ti a ti nba ara wa bo koda mo ti mu arakunrin yi lo Odo awon obi mi, ti a si ti n gbero lati se idano. Sugbon ni osan ojo abameta kan ti mo lo ki arakunrin yi ni ile, nse ni ero ibanisoro mi yonu ni ojo na, ti mo si nilo lati pe egbon mi ti won je akobi wa, se ori simu kadi mi ni onka ero ibanisoro won kuku wa. Ni mo be arakunrin yi ki o ya mi ni ero ibanisoro re, ki n fi siimu mi sii lati fi ri onka ero ibanisoro egbon mi.

 

Bi mo ti fi siimu mi si inu ero ibanisoro alagba yi, ni ore won kan wole de, ti mo si wonu iyara lo, ki n maa ba di won lowo, koda nko mo ohun ti mo te ninu ero ibanisoro yi, sa dede ni mo ri opo itakunroso alagba yi ati obinrin kan, ti won si n soro bii loko-laya. Opolopo itakunroso wonyi ni mo ri ni ori wasabu arakunrin yi ati opo miran ni abala atejise. Awon oro wonyi wa n se mi ni kayefi. Logan ti ore arakunrin yi lo tan, ni mo pee ti mo si fi awon itakunroso wonyi han an, ti mo si bii wipe ta ni eni yi gan? Alagba yi si wa tenu bo oro wipe

“Ni ikorita ti a de yi, mo Setan lati so ododo oro fun e, woo mo fi Eleda awon obi re mejeeji be o darijimi, ife ti mo ni si o ni ko je ki n le so okodoro oro fun o lati eyin wa, tori mo se akiesi wipe ti o ba mo wipe mo laya nile, o ni gba fun mi, idi niyi ti mo fi daa bi ogbon. Iyawo meji ni mo ti fe ri sugbon okan ti se alaisi ti ekeji si wa pelu mi di oni. Jowo mo fi Olorun be o, darijimi, mo ni ife re tokantokan ni, mo si setan lati fi o se aya”

Bi alagba yi ti n so oro ni omi n da loju mi, looto kii se oro yi ni o ngbomije loju mi bikose oro igbesi aye mi nitori eyi kii se akoko ti iru Isele yi yoo se simi. Bi arakunrin yi ti danu duro, ni mo daa lohun wipe mo ti gbo, ti mo si kuro niwaju re. Ti mo kori si ona ile mi, mo wa nro oro na lati ojo na koda o toju sumi, abi ta ni yoo gbadura ile olorogun fun ara re, obinrin wo ni inu re yoo dun lati gbo wipe obinrin miran n fe oko oun?

Awon ibeere wonyi ni mo n bi ara mi, ni mo fi oro yi lo egbon maami kan tori maami ko si laye mo. Ni won si wipe pelu gbogbo alaye mi wonyi, o seese ki o je ayanmo temi niyen. O seese ki o je okunrin ti o laya nile ni a ko mo mi lati fi se ade ori. Mo wa n da oro yi ro wipe se o seese ki Olorun ko iru nkan bayi mo eniyan? Nigba ti nko ri idaun si ibeere yi, ni mo fi oro na lo egbon mi kan ti won je alagba ijo. Egbon mi yi si wa nje ki o ye mi wipe, Olorun kii ko ikokuko mo eniyan, won tesiwaju wipe nigba ti Aseda seda awa eniyan, tako-tabo ni o seda wa, beeni gbogbo ohun abemi pata. Olukuluku okunrin ti Eledua seda ni o seda aya re pelu, bakan na si ni gbogbo obinrin pelu. Nitorina ki n ma daba ati fe oko oloko o, ki n duro de akoko Eledumare fun oko temi gan tori oko kan aya kan ni bibeli wi. Nitorina ki n tesiwaju ninu adura, wipe awon pelu yoo maa ran mi lowo ninu adura.

Awon oro wonyi wa n gba omije loju mi abi odun melo ni oluware yoo fi duro bayi? Iyen ni mo se ni ki n gba amoran lenu eyin oloye eniyan. Se ki tesiwaju ninu adura gege bi alagba se wi ni, abi ki n gba kadara, ki n si maa tesiwaju pelu arakunrin yi? E jowo e la mi loye o

Hmmm oro ree o, eyin ojogbon eniyan, e jowo e ba wa fi oju sunukun wo oro ile yi. Se ki arabinrin yi kese bo bata ile olorogun ni abi ki o tesiwaju ninu adura?

`Abel Simeon Oluwafemi

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti