Home / Art / Àṣà Oòduà / Odo Iwoyi – E Gbo Bi Atejise Na Ti Lo
omo yoruba atata

Odo Iwoyi – E Gbo Bi Atejise Na Ti Lo

Mo ki gbogbo wa pata lokunrin ati lobinrin, lomode ati lagba wipe a ku ise oni, a si ku abo sori eto wa eto yin, eto Odo Iwoyi ti ose yi. E wa nkan fidile tabi ki e gbiyanju fidile nkan, ki a jo gbadun ara wa bi ijebu ti ma n gbadun gari.
Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon Ololufe eto yi ni a o maa ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won lamoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO;……
“Olootu mo ki yin fun ise takuntakun ti e nse lori eto yi, Eledua yoo san yin lesan ire o, Amin. Mo si ki gbogbo eyin ojogbon ati oloye eniyan ti e n da seto yi, Eledua yoo da soro aye enikookan wa na o Amin.
E jowo olootu oro kan ni o sebi oro laarin emi ati awon obi mi, ti oro na si se mi ni kayefi, iyen ni mo ni ki n fi to awon ojogbon eniyan leti, ki n le mo asise mi, ki awon odo egbe mi pelu si le kogbon nibe. Eni odun metadinlogbon ni mi, odun ti o koja ni mo setan ni ile eko ifasiti, ki n to setan ni ile eko ni maami a ti ma pe mi si ikoko, ti won a si maa so fun mi wipe, pelu ojo ori mi, o ti ye ki awon ti mo eni ti mo n fe gege bi afesona, sugbon nse ni mo ma n fun maami ni suuru wipe ohun gbogbo ni akoko wa fun, wipe kii se wipe nko ni eni ti mo nfe sugbon ti nko ba pari eko mi n ko le mu okunrin wa sile.
Leyin ti mo ti wa setan bayi, ni mo pe maami ti mo si fi to won leti wipe mo fe mu afesona mi wa ki o le mo awon obi mi, inu maami si dun si igbese yi pupo, maami si wa so fun mi wipe ki n fi oro na to baba mi leti, beeni mo se bi won ti wi, inu baami pelu dun nigba ti won gbo oro yi. Beeni a fi ohun gbogbo si ojo abemeta ti o koja lo yi.
Ibi igbafe kan ti o wa ni gbagede inu ogba ile wa, ni a joko si ni ojo ti mo nso yi, ibi igbafe yi ko jina si ibi ti a ma n ko oko ayokele wa si, ibe ni baami feran lati ma joko si nitori ategun. Ki n ma fa oro gun, ko pe ti a nfi oro jomitoro oro, ni afesona mi de, oko ayekole re ni o gbe wa, bi o ti de ni asona ile wa si enu ona fun-un ti o si gbe oko re wole, se ibi ti a kuku n gbe oko si ko jina si ibi ijoko wa, bi arakunrin yi ti jade ti mo si lo pade re ni a di mo ara wa ti a si fi enu ko ara wa lenu, bi a ti de ibi ti maami ati baami joko si, arakunrin yi ki won bi o ti ye.
Leyin iseju die ti arakunrin yi ti wa ni ijoko, ni baami tenu bo oro ti won si beere opolopo ibeere lowo arakunrin yi, maami pelu beere awon ibeere kookan, leyin bi wakati kan le die, ni arakunrin yi toro aye lati maa lo, beeni baami si fun-un laye koda won se adura fun arakunrin yi pelu. Bi o ti dide ni emi na dide, ti mo si tele de idi oko bi o ti fe wo inu oko ni a di mo ara wa ti a si tun fi enu ko ara wa lenu, beeni mo pada si ibi ti awon obi mi joko si pelu erin.
Sugbon iyalenu ni o je wipe, nigba ti n o fi pada de ori ijoko, mo se akiyesi wipe nse ni oju baami kore lowo, ni baami si pe oruko mi lemeeta, ti won si wipe
“Emelo ni mo pe o? Woo o koi ti r’oko o, duro na, se mo jebi ni bi mo se ran o lo ile eko ni? Se ese ni bi mo se na owo le o lori ni? Se ile eko ti mo ran o lo ni o gba iwa omoluabi kuro lara re ni? Se ti iwo o ba tie gbon, se daginidagini ti o pe ni afesona re owun ko ni lakaye ni? Nibo ni e ti ri iru asa buruku yi ni ile Yoruba? Okunrin ti koi ti san owo ori re, wa n ti enu bo o lenu niwaju mi!! Iru asa palapala wo ree? Woo nko gbudo tun ri okunrin yi ni ayika ile mi yi mo ti o ba mo wipe emi ni mo bi o”
Bi baami ti soro tan, ni won fe dide pelu ibinu, beeni maami wipe, “Dadi e dakun e mai ti lo, looto iwa ti won hu ko bojumu to, sugbon sibe, se e mo wipe omode ni won, a o maa to won sona ni, mo ro wipe nse ni o ye ki a pe awon mejeeji, ki a si ba won soro tori won le ma moo si iwa aida”
Ni baami wipe “Pe awon tani, ennn mo mo wipe eyin won ni iwo na yoo waa, woo ibi ti o ba ba aye awon omo wonyi je de, e o jo maa yanju re, temi ni wipe nko fe ri ogbeni yen mo ni ayika mi”
Bi baami ti dide ree, ti won si wonu iyewu won lo, nse ni emi ati maami wa nwoju ara wa, ni mo n bi maami wipe, se nkan miran wa lori oro ile yi ni? Abi ki ni o buru ninu ki emi ati afesona mi fi enu ko ara wa lenu? Oro yi ko tie fe yemi mo, koda nko gbo iru re ri. Leyin isele yi mo gbiyanju lati lo ba baami sugbon nse ni won wipe toba se lori oro afesona mi yen ni, nko gbudo tun soo leti awon mo. Iyen ni mo se ni ki n fi oro na to eyin oloye eniyan, ki e tun ba wa dasi, e dakun ki ni o buru ninu iwa ti a hu yi gan? E jowo se igbese ti baami pelu gbe yi si bojumu to? Mo ro wipe ti ife ba ti wa laarin ololufe meji kekere ni awon eyi ti o ku abi? Emi ati afesona mi yi si ni ife ara wa, se o wa ye ki o je oro a ntenu bo ara wa lenu loju awon obi mi ni baami yoo fi da arin wa ru bayi? Eyin baami ati maami nile, eyin ologbon ati oloye eniyan, oro ree o, e jowo e ba mi dasi o……”
Hmmmm oro ree o, eyin ojogbon eto Odo Iwoyi, gege bi e ti mo wipe ise ati asa Yoruba ni o je wa logun ni abala yi, ki ni asa Yoruba so lori oro yi? Nje iwa ti arabinrin yi ati afesona re hu ba asa Yoruba mu? Nje igbese baba yi pelu ba ise Yoruba mu? Nje mama arabinrin yi soro bi Yoruba bi? Ta ni ki a tie da lebi gan lori oro yi? Se okunrin ti ntenu bo afesona re lenu loju awon obi re ni? Se obinrin ti o koyan awon obi re kere loju afesona re ni? Se baba ti o fe da igbeyawo omo re ru nitori ifenukonu lasan ni? Se iya ti ko faramo igbese baba omo re ni?? Ju gbogbo re lo, ki ni amoran yin fun arabinrin yi gan? Igbese wo ni ki o gbe bayi ki oro ile yi le ni iyanju, se ki o se bi baba re se wi ni abi bo?? Eyin oloye eniyan oro ree ooo.

`Abel Simeon Oluwafemi

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti