Mo ki gbogbo Omo Yoruba Atata pata nile-loko ati leyin odi wi pe a ku dede asiko yi, mo si ki awa ololufe eto Odo Iwoyi wi pe e ku abo sori eto wa, eto yin, eto Odo Iwoyi ti ose yi. E wa nkan f’idi le abi ki e f’idi le nkan ki a jo gbadun ara wa bii ti ateyin wa.
Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon ololufe eto yi ni a o maa Ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won nimoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO:-
“Olootu mo ki yin pupo fun ise takuntakun ti e nse lori eto Odo Iwoyi, Eledua yoo wa pelu yin o, e jowo olootu oro emi ati afesona mi ni mo fe ki e ba mi gbe sori eto ki awon ojogbon ati oloye eniyan le la mi loye.
Odun Keji ree ti emi ati arabinrin yi ti nba ara wa bo, ti nko ba ni paro mo ni ife arabinrin yi ti mo si mo wi pe oun pelu ni ife mi, agbegbe kan na ni emi ati maami ngbe sugbon adugbo otooto ni adugbo wa. Omo meta si ni maami bi ti mo si je okunrin kansoso laarin won, beeni emi si ni abikeyin ile wa, awon egbon mi obinrin mejeeji si ti rele oko won.
Ni osu ikefa odun yi ni mo mu afesona mi lo ki maami, ti won si gba awa mejeeji lamoran pelu opolopo adura, ni bi ose meji seyin ni emi ati afesona mi yi n ti ode kan bo ti a si ro wi pe ki a ya odo maami niwon igba ti o je wi pe adugbo won ni a o gba koja. Bi a ti ki maami tan ti a si fe maa pada ni maami pe mi seyin ti won si wi pe :-
“Olowo ori mi, se o mo wi pe emi ati Eleda mi ni a jo n sun ti a jo n ji lati igba ti baba re ti se alai
si? Beeni agba si ti n de die die bayi, o si dakun ba mi ba iyawo re soro bi o se ekan laarin ose meji, ki o maa wa ba mi fo awon aso mi, Eledua yoo kuku je ki e pe fun ara yin, esu o ni ko si yin laarin lase Edumare, joo ba mi baa soro”
Bi maami ti danu duro, ni mo ki won ti mo si se adura wi pe, Eledua yoo je ki won pe fun wa, beeni mo se ileri wi pe n o ba arabinrin na soro, ti mo si mo wi pe yoo gba si mi lenu tori omo ti a ko ti o gbeko ti o si ni iteriba fun agba ni omo na. Inu maami dun pupo lati gbo oro yi, ti won si tun se opo adura leyin eyi.
Bi a ti nlo lona ni mo menu ba oro yi fun afesona mi sugbon iyalenu ni o je fun mi owo ti arabinrin yi fi mu oro yi, nse ni o daun wi pe:-
“Woo kii se wi pe nko le foso mama o, sugbon kii se lowo ti a wa yi, abi nibo ni won ti nse iru re? Se o ti san owo ori mi ni? Ki wa maa fo aso mama re leekan laarin ose meji? Se mo ti di iyawo sara ni? Ma si mi gbo o, kii se wi pe nko lee se ohun ti mama beere o sugbon kii se ni akoko yi, ti o ba ti se eto lori mi, koda ki mama maa gbe pelu wa, mo setan lati maa foso won lojoojumo, sugbon lowo yi, ki a ma rii ni Poolu wi”
Bi arabinrin yi ti danu duro ni mo mi kanle ti mo si so fun un wi pe ki o menu kuro nibe, bayi ni a janu lori oro yi, sugbon oro yi a maa so si mi lokan ti un a si maa da jiroro lori re. Se ti a ba dake nse ni oro ara wa yoo kuku ba wa dake, ni mo se alaye oro yi loju awon ore mi meji kan boya mo le ri amoran ti n o tele, sugbon ohun awon ore mi mejeeji ko sokan eyi ni mo se ni ki nfi oro na lo eyin ojogbon, nse ni ore mi akoko wi pe :-
“Ogbeni Yoruba bo won ni oju ti yoo ba ni kale, ati owuro ni a ti n mo, obinrin ti ko tii wole ti o ti n fowo lale fun o bayi, ti o nwipe oun o le foso iya oko oun, se iru obinrin be yoo fo ti iwo oko gan toba de ile tan, o je tete ronu re wo, tori eniyan kii tese bo o, ki o tun weyin o”
Beeni ore mi keji daun wi pe
“Haaaa aaaa kilode ti o je idi ko baje ko baje ni iwo wa bayi? Woo ore, ma je ki won si e lona o, sebi o nife arabinrin owun? Emi o rohun to buru ninu ohun ti arabinrin yi so o, abi iwo o mo wi pe bi eni tara eni lopo loro na ri? Bawo ni o se wi pe ki obinrin ti o koi tii gbe sile maa lo fo aso iya re? Woo ore, emi kii ba won da ile onile ru o, ma je ki won si e lona o, tete fa iyawo re mora o”
Hmmmm ni mo mi kanle, ti mo si ki awon mejeeji,mo wa nronu oro yi sugbon ko yemi rara, iyen ni mo se ni ki nfi oro yi lo eyin ojogbon ki e jowo la mi loye ki n ma ba s’ese gbe. Olootu oro mi ko ju bayi lo o, Eledua yoo je ki a maa ri yin ba o.
Hmmmm oro okunrin ati obinrin afi ki Eledua ran wa lowo o, eyin baba ati maami nile, eyin ojogbon ati oloye eniyan, e gbo oju wo ni eyin fi wo oro yi, ki ni amoran yin gan fun arakunrin yi? Se arabinrin yi jebi pelu oro re yi abi ki a wi pe ohun ti mama yi bere fun ku die kia to ni? E jowo e ba wa dasi o
Abel Simeon Oluwafemi