Mo ki gbogbo Omo Yoruba Atata pata nile-loko ati leyin odi wi pe a ku dede asiko yi, mo si ki awa ololufe eto Odo Iwoyi wi pe e ku abo sori eto wa, eto yin, eto Odo Iwoyi ti ose yi. E wa nkan f’idi le abi ki e f’idi le nkan ki a jo gbadun ara wa bii ti ateyin wa.
Gege bi ise wa lori eto yi, atejise kan ti a ri gba lati owo okan lara awon ololufe eto yi ni a o maa Ka si wa leti loni, ki a jo fi oju sununkun woo, ki a si gba won nimoran bi o ti ye. E GBO BI ATEJISE NA TI LO:-
“Olootu mo ki yin pupo e ku atunse lotun losi, Eledua yoo tun ile ati ona tiyin na se lase Edumare.
Olootu e jowo omodebinrin kan ni o fi oro kan lo mi ti mo si ni ki n fi to awon ojogbon leti tori won ni ogbon o pin sibi kan. Looto omo yi kere simi lojo ori pupo sugbon se awon agba ni won kuku wi pe ti omode ba mo owo we yoo kuku ba agba jeun.
Omo yi je akikanju omo, omo ti eniyan fi ntoro omo si ni pelu, gbogbo abiyamo adugbo ni won ma n fi omodebinrin yi se akawe oro fun awon omo won, Arabinrin yi je omo jeje, o ni iteriba, kii roju se ise, lakaye ori omo yi ju ti agbalagba miran lo.
Ibi itaja kan na ni emi ati iya omo yi wa, tosi je wi pe omo yi ni o n se kokari oja iya re, eyi ni o fa ti emi ati omo yi fi sun mo ara wa, koda nibi ti mo feran omo yi de, un a maa fi oro emi ati oko mi lo arabinrin yi lopo igba ti yoo si fun mi ni amoran ti o dara. Sa dede ni omo yi pe mi ni ojo isegun ti o koja lo yi ti o si tenu bo oro bayi wi pe-:
“Momi e ku oja ano, awon dadi nko? e woo momi, mo ni oro kan ti mo fe so fun yin, bi o tile je wi pe, mo ti pinnu wi pe nko ni so oro yi fun enikan sugbon gege bi owo ti e fi mu mi ti nko ba so fun yin eri okan yoo maa je mi, e woo bi mo ti wa yi nko gbonju mo baba ti o bi mi lomo, gege bi alaye ti mo gbo lenu maami, omo odun meta ni mo wa ti baami fi di oloogbe, igbagbo maami si ni wi pe awon ebi baami ni o seku pa baami nitori awon dukia ti won ni, idi niyi ti maami fi gbe mi sa jina rere si awon ebi baami, eni odun marun ni mo wa ti maami fi fe okunrin miran ti won wa nile re titi di akoko yi, omo meta ni maami si ti bi fun oko won tuntun yi, awon isoro ti mo wa ndojuko gan ree, ile eko alakobere nikan ni mo lo, bi e si ti nwo mi yi, eni odun mejilelogun ni mi, nko Ka iwe ju iwe mefa lo beeni nko si ni ise kan lapa, mo si ti ba maami soro lopo igba ki won je ki n lo ko ise sugbon nse ni maami nkoti ikun si oro yi, mo ti ba won so oro yi lopo igba sugbon nse ni maami o ri temi ro, mo wa se akiesi wi pe oja ti mo nba maami ta ni o je won logun, won o ba mi ronu ojo ola mi, mo si ma n ronu oro yi lopo igba, beeni mo se akiesi wi pe opo awon okunrin ti o wa laye ode oni ko setan ati fe obinrin ti ko kawe ti ko si nise lapa, idi niyi ti mo se pinnu lati sa kuro lodo maami ki n si wa bi ojo iwaju mi yoo se ni itunmo lo.
Looto nko ni ibi kan pato ti n o lo bayi sugbon mo mo wi pe Eleda baba mi yoo dari mi, Koda oro yi ti je ki ngbena wo oju maami ni akoko kan ti ko si dun mo mi ninu, ti mo si so fun won ni akoko na wi pe ti won ko ba setan ati ran ojo ola mi lowo n o sa kuro fun won ni. Ni maami so pelu ibinu nigba na wi pe ti n ba dan iru re wo, awon yoo gbe mi sepe ni ayafi ti awon o ba se wahala lori mi. Sugbon ni bayi mo ti pinnu wi pe ti won yoo ba gbe mi sepe ni ki won gbe mi sepe iyen ni mo se ni ki n fi to yin leti tori eyin agba na ni e wi pe, a kii soosa lodo ki labelabe ma mo, ohun ni mo se ni ki n fi to yin leti o”
Hmmmm ni mo mi kanle ti mo si wi pe, o ma ga o, se wi pe awon dadi ko ni baba ti o bi o lomo? Haaa o ma ga o, woo suuru ni oro ile yi gba o, tori okun kii wo ruru ki a waa ruru, ti a ba si ni wi pe ki a da ina ejo bi o ti gun to afaimo ki a ma dano sun ile, tobe jube lo maa lo ta oja re na, n o ba o soro toba di opin ose, ki Eledua so wa ju akoko na lo.
Olootu oro owun ko ju baun lo o, iyen ni mo ni ki nfi lo awon ojogbon ki won ba mi da si oro yi tori nko fe ti omode yi sina beeni oja Ola re si je mi logun pupo.
Oro ree o eyin ojogbon, se eyi o wa so sini lenu bayi, abi aa ti gba omo lamoran ki o tapa sofin iya to bii lomo, bawo si ni a o ti da omo lekun ki o ma sare ojo ola re? Eyin oloye eniyan, oro re e ba wa dasi o
Abel Simeon Oluwafemi