Home / Art / Àṣà Oòduà / Odu ifa IROSUN OPINNI/ IROSUN ORO
opn ifa

Odu ifa IROSUN OPINNI/ IROSUN ORO

| |
| |
| | | |
| | |

 

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, gegebi oni se je ojo isegun olorun alagbara yio muwa bori Ogun ota ase.
Odu ifa IROSUN OPINNI/ IROSUN ORO lo gate laaro yi, ifa yi gba eniti odu yi ba jade si niyanju wipe ki o rubo daradara nitori aarin ota Omo araye lo wa, ifa ni won maa jowu re beeni won si maa se inunibini si sugbon nipa etutu yio segun won.

Ifa naa ki bayi wipe: irosun reterete babalawo oro difa fun oro lojo ti oro nbe laarin ota Omo araye won ni ki o karale ki o rubo ki o baa le segun won, ki o baa si le di eni nla nibikibi yio wu ki won gbe lo si, obi meji, obuko, epo pupa, iyo oro kabomora o rubo esu si gba ebo re nigba kutukutu iwase inu ira ni oro wa seni omo araye se inunibini re ti won si si kuro nibe ti won gbe lo sori apata, nigbati o tun dori apata seni esu odara lo gba yepe sidi re bee lo tun ntobi esu odara wa ki egugun obuko ti oro fi rubo si lara o sin da iyo si lara, oro wa bere sini tobi, beeni inu tun bi awon ota won tun sope won maa si oro kuro lori apata to wa yen ibiti won ti lo nge oro seni oje igi oro ta siwon loju, seni oju wa ntawon bi won se salo niyen o lati ojo naa ni oro ti segun awon ota re oro wa njo o nyo o nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nba awo lese obarisa.

 

Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe ibiti o wu ki awon ota da ori wa ko ao se rere nibe, ota kota to ba sope oun fe ge wa kuro lori ile yio fo loju lesekese ao si se gbogbo ogun awon ota to dojukowa o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

English  Version:

Good morning my people, how was your night? Hope you slept soundly, as today is Tuesday, a victory’s day may almighty father help us to conquer the power of our enemies ase .
It is IROSUN OPINNI/ IROSUN ORO corpus that revealed this morning, ifa advised whoever this corpus revealed out for that he/she should offer sacrifice because of the war of enemies, ifa said there would be a jealous from enemies because of his/her prosperity and those enemies will want to trying to kill him/her.

 

Hear what the corpus said: Irosun reterete the priest of oro plant cast divined for oro plant when oro was at the midst of enemies, oro was advised to offer sacrifice so that whatever enemy do to it, it will prosper, two kola nuts, he-goat, salt, palm oil and oro complied, oro was located at swamp area before and it was very big but the enemies persecuted it they shift oro from its position to the surface of rock, when oro reached the surface of rock esu odara has eating its sacrifice and he put sand to the bottom of oro plant and oro started germinating esu odara put the bone of he-goat that oro offered as a sacrifice on its body and he also put salt too to its body, when enemies saw that oro has became big they went there with cutlass to cut it off, when they cut it the water of oro splashed into their eyes and it was very peppery they shouted and they ran away, that is how oro plant conquered its enemies oro started dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa while ifa was praising God.

 

My people, I pray this morning that wherever enemy plan to shift us to,we shall succeed there and prosper, and enemy that want to trying to cut us down will become blind immediately and we shall conquer all the wars that enemy is waging against us amen.

 

Faniyi David Osagbami

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

16 Ofun Meji

Ifa: The 16 Odu Ifa & Their Meaning.

The meaning of the 16 Odu Ifa of the Ifa is based on 16 symbolic or allegorical parables contained in the 16 Core Chapters or Principles that form the basis of the Ifá, a system of divination of the Yoruba people of Nigeria. The Grand Priest of Ifa, the Babalawo or Iyanifas are the Priests and Priestesses of the Ifa Oracle that receive and decode the meaning of the Divine Messages contained in the Odu Ifa Parables that are transmitted ...