Home / Art / Àṣà Oòduà / Odu Ifa Owonrin Alakara/ Ika
ifa verse

Odu Ifa Owonrin Alakara/ Ika

| |  | |
| |   |
| |   |
| |   |

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a sin tu ku isimi alayo loni eledumare yio funwa ni isimi to peye emin wa yio si se pupo re lori oke yepe ase.  Odu ifa OWONRIN ALAKARA/IKA lo gate laaro yi, ifa yi fore ayo, idunnu ati okiki rere fun akapo ti odu ifa yi ba jade si, ifa ni akapo yi yio gba awon alejo kan ifa ni ki o toju awon alejo naa daradara nitori won yio ko orire ba ti yio di olokiki ati eni ibowo fun laye, ifa ni ki akapo yi ni opolopo akara ki o fi bo ori re ki opolopo awon eniyan si ba je akara naa.
Ifa naa ki bayi wipe: Owonrin kaara akara kaara a difa fun orunlojo Omo irunmole lojo ti won fe lo fi ile akara se ibugbe won ni ki akara karale ebo ni ki o se nitori ki o baa le gba alejo ti yio so di olokiki ati ologo nile aye, obi meji, agbalagbulu epo pupa, ogo iyo ati igba ewe ayajo ifa akara si kabomora o rubo won si se sise ifa fun, nigbati o maa di ojo Keji seni gbogbo Omo irunmole wo kunnu ile akara ti won bere sini ngbe akara jo ti won ngbe akara yo leyo kookan lati igba naa ni akara ti di eni agbejo agbeyo o si di olokiki, o wa njo o nyo o nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni nje riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami ni jebutu ire nje jebutu ire ni a nba awo lese obarisa.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe eledumare yio ran alejo ti yio sowa di olorire laye siwa loni, gbogbo adawole wa yio maa yori si rere akara yio kawa mo awon olorire eniyan , ologo ati alalubarika aye, a koni rare nile aye wa o nitori akara ki nrare lagbada aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

English Version:

Good morning my people, how was your night? hope it was fantastically enjoyed, wishing you all a beautiful Sunday may God in his mercy make us witness many more on the earth amen.
It is OWONRIN ALAKARA/IKA corpus that revealed this morning, ifa foresee a great blessings, dignity and prosperity for whoever this corpus revealed out for, ifa said this person should be entertaining any visitor that may pay him/her a visit so that his/her glory may be progressing, ifa advised him/her to use akara(cake beans) to feed his/her head and he/she should give people to eat .
Hear what the corpus said: Owonrin kaara akara kaara it cast divined for “Akara”(cake beans) when all deities will make his house for their abode, akara was advised to offer sacrifice so that he may receive a good visitors that will make him become famous and prosper in life, two kola nuts, palm oil, salt and ifa leaves and he complied the ifa medicine was prepared for him, when it was second day all deities came down to akara’s house, they started carrying akara one by one with dancing, this is how akara became respected and famous, he started dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa while ifa was praising God.
My people, I pray this morning that God will send a visitor that will make us becomes a rich person today, we shall be prosper in all our endeavors, akara will count us among the successful people of the earth and we shall never suffer anymore because akara do not suffered inside a frying pan amen.

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

One comment

  1. That odu sign is not owonrin alakara/ika, its osa/oyeku

x

Check Also

Prof. Moyo Okediji Turns A Day Older today

Today is the birthday of professor Moyo Okediji. Let’s join hands to wish him longevity and sound health. 256 odu ifa Signatures © Ifa University Photo/Moyo Okediji 256 odu ifa Signatures © Ifa University Photo/Moyo Okediji