Home / Art / Àṣà Oòduà / Ofin mokanla to le mu awo ara dabi omo tuntun jojolo
baby

Ofin mokanla to le mu awo ara dabi omo tuntun jojolo

Orisun
1 E yee sa ara yin sinu oorun koja bo ti ye lo. Paapa julo, e sora fun awon oorun lati bi ago mewaa aaro si ago meji osan. Orisii oorun yii a maa mu ki awo eniyan o sa.

2. E ri wi pe e n se imototo awo ara yin nigba gbogbo. E yago fun awon ose alagbara to le mu awo yin maa bo.

3. Ounje lore awo. Eri daju wi pe e n je awon ounje to peye. Awon ounje bi efo ati eso yoo se iranwo fun awo ara yin gan-an.

4. E yago fun siga ni mimu. Iwadii fi ye wa wi pe siga a maa je ki awo eniyan hunjo. A si maa mu ni dabi arugbo laipe ojo.

5. Ti eniyan ba n fi ara re sise ju bo ti ye lo, o le se akoba fun awo ara bakan naa.

6 E ri wi pe e n mu opolopo omi. Opolopo omi dara ni mimu fun itoju awo ara.

7. E ri daju wi pe e n fi omi boju yin ki e to sun lale ati igba ti e ba ji laaaro. Sise awon nnkan bayii loorekore a maa je ki oju yin jolo bi oju omo tuntun jojo lo.

8. E je ki a maa se imototo foonu wa. Paapa julo awa ti a n lo glass touch-screen. Aimoye kokoro aifojuri lo le wa lara foonu naa eleyii ti o le sakoba fun awo ara wa. A le maa lo Clorox Disinfecting Wipes lati maa nu oju foonu naa nigbagbogbo.

10. Fun awon obirin, e ri daju wi pe e n fo gbogbo atike, itoju ati itote to wa loju yin ko to di wi pe e bo sori beedi lati sun lale. Aimoye orisii eroja ni won fi se iru awon nnkan bayii to je wi pe o le sakoba fun awo ara eni to ba peju bo ti ye lo lara.

11. Bakan naa, fifi omi gbigbona to gbona lagbona ju we le se akoba fun awo ara wa. Paapa ju lo fun awon ti ojo ori won ti le ni ogoji odun.

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti