Òhun tí Ọlọ́run ṣe fúnmi ju n tó tọ́ sí mi lọ— Ọbasanjọ
Olóyè Ọbasanjọ, gẹ́gẹ́ bí ara ètò fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún kẹtàlélọ́gọ́rin rẹ̀ léwájú àwọn èèkàn lọ síbi àpèjẹ pàtàkì kan fún àwọn àlejò gbogbo.
Olóyè Ọbasanjọ pé ẹni ọdún mẹtàlélọ́gọ́rin ní ọjọ́ karùn- ún oṣù kẹta ọdún 2020.
Òdú ni Olóyè Ọbasanjọ lẹ́ka òṣèlú nílẹ̀ Nàìjíríà àti lágbàáyé èyí ló sì sọ ilé rẹ di ibùdó àti gba ìmọ̀ràn fún olúkúlùkù àwọn èèkàn àti aṣíwájú ìlú gbogbo káàkiri orílẹ̀-èdè àgbáyé.
Olóyè Ọbasanjọ jẹ́ atàpátadìde tí Èdùwà fún láàyè láti darapọ̀ mọ́ iléeṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó di Ọ̀gágun àgbà, ó di olórí ìṣèjọba ológun lọ́dún 1976. Òun sì ni olórí ológun àkọ́kọ́ nílẹ̀ Áfírìkà tí yóó fínúfíndọ̀ gbé Ìjọba sílẹ fún alágbádá lọ́dún 1979.
Bàbá, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe máa ń pèé, bọ́sí agbo òṣèlú lọ́dún 1998 lẹ́yìn tó ti ọgbà ẹ̀wọ̀n tí Ìjọba ológun lábẹ́ Ọ̀gágun Sani Abacha rán an lọ, dé.
Lọ́dún 1999 ni Ọbasanjọ di Ààrẹ alágbádá kejì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, kí àwọn ọmọ Nàìjíríà tó tún yàn án sí ipò náà fún sáà kejì lọ́dún 2003.
Fẹ́mi Akínṣọlá