Home / Art / Àṣà Oòduà / Omidan asewo ti se ‘kerewa’ koja sorun alakeji
Oku Ome Enyi

Omidan asewo ti se ‘kerewa’ koja sorun alakeji

Awon Yooba bo, won ni owo tada mo ni kada lehin. Iku ogun ni i pa akikanju, omi ni pada wa pa omuwe lodo. Okan ninu awon omo asewo ilu Abuja ti oruko re n je Omidan Ome Enyi lo ti se agbako iku ojiji bayii lenu ise nabi to yan laayo. Omobirin eni odun marunlelogbon (35) ni won ba oku re ninu ile itura kan to wa ni agbegbe Kubwa to wa niluu Abuja. Ome to je omo ilu Calabar lagbo wi pe oun ati okan ninu awon onibara re kan jo wole sun lale ojo Aje to koja yii fun “igbadun alailopin”.

 

Sugbon nigba ti ile yoo fi mo, oku Ome nikan ni won ba nile gelete. Okan ninu awon agbale ile itura naa lo sakiyesi oku omobirin naa ki won to gbe lo si ile igbokusi. Titi di akoko akojopo iroyin yii, enikeni ko ti le so pato iru iku to pa omidan orekelewa ti n fidi re pawo naa. Bakan naa ni ko si eni mo ibi ti onibara re fara pa mo si.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

taniolohun

Esin Ajeji Pelu Ete