Ẹ̀bùn Edùmarè ni ọmọ
Ẹ̀rí ìfẹ́ rẹ̀ sí wa ni wọ́n
Èdùmàrè à ń bẹ̀ ọ́
Bá wa wo àwọn èwe yè
Fi wọ́n fún àwọn tí ń wojú rẹ fún ẹ̀bùn wọn
Má ṣe jẹ́ kí wọ́n kú mọ́ àwọn òbí wọn lọ́wọ́
Èyí a wí yìí, kárọ̀ rọ̀ mọ́ ọn.
@AlamojaYoruba
Fẹ́mi Akínṣọlá Ádùrá tí a máa ń ṣe ni pé kí á má rin àrin f’ẹsẹ̀sí.Mọ̀lẹ́bí ọkùnrin kan, Ògbẹ́ni Olaoye Olatunde, tó jẹ́ igbákejì ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ girama kan nílùú Ọwọ ti ké gbàjarè pé ọkùnrin náà di àwárítì lẹ́yìn tó lọ fún idanilẹkọ ní ilé ìtura Sunview nílùú Akure. Iyawo arakunrin naa salaye rẹ pe, ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹjọ, ọdun 2025, ni ọkọ rẹ dagbere pe ohun n lọ fun idanilekọ kan n’iluu Akure, eyi ti wọn ...