Home / Art / Àṣà Oòduà / Oríkì Àjọbí, Àṣà Yorùbá ti ó Nparẹ́ lọ
asa yoruba

Oríkì Àjọbí, Àṣà Yorùbá ti ó Nparẹ́ lọ

Oríkì* jẹ ọ̀rọ̀ ìwúrí ti Yorùbá ma nlò lati fi sọ ìtàn àṣà àti ìṣe ìdílé lati ìran dé ìran. Ninú oríkì ni a ti lè mọ ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ ẹbí ẹni àti ohun ti a mọ ìdílé mọ́, bí i irú iṣẹ ti wọn nṣe ni ìdílé, oriṣiriṣi èdè ìbílẹ̀ Yorùbá, oúnjẹ ti wọn njẹ àti èyí ti wọn ki i jẹ, ẹ̀sìn ìdílé, àdúgbò ti wọ́n tẹ̀dó si tàbi ìlú ti a ti ṣẹ̀ wá, àṣeyọrí ti wọn ti ṣe ni ìran ẹni àti bẹ́ ẹ̀ bẹ́ ẹ̀ lọ.

 

Ni inú oríkì ti a ó bẹ̀rẹ̀ si i kọ, a ó ri àpẹrẹ ohun ti Yorùbá ṣe ma a nsọ oríkì pàtàki fún iwuri nigbati ọkùnrin, obinrin, ọmọdé àti ẹbí ẹni bá ṣe ohun rere bi ìṣílé, ìgbéyàwó, àṣeyorí ni ilé-iwé, oyè jijẹ tàbi ni ayé òde òni, àjọyọ̀ ọjọ́ ìbí.

 

Oríkì jẹ ikan ninú àṣà Yorùbá ti ó ti nparẹ́, nitori ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Yorùbá bẹ̀rẹ̀ si kọ èdè àti àṣà wọn sílẹ̀ fún èdè Gẹ̀ẹ́sí. Ẹ ṣe àyẹ̀wò àpẹrẹ oríkì ti ìyá Olùkọ̀wé yi sọ fún ni ibi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀ ni ojú ìwé yi. A ó bẹ̀rẹ̀ si kọ oríkì oriṣiriṣi ìdílé Yorùbá.
Ọmọ ẹlẹ́ja ò tú mù kẹkẹ
Ọmọ a mẹ́ja yan ẹja
Ọmọ ò sùn mẹ́gbẹ̀wá ti dọ̀ ara rẹ̀
Ọmọ gbàsè gbàsè kẹ́ ṣọbinrin lọyin
Ọmọ kai, eó gbé si yàn ún
Ọmọ a mú gbìrín eó b’ọ̀dìdẹ̀
Ìṣò mó bọ, òwíyé wàarè
Ọmọ adáṣọ bù á lẹ̀ jẹ
Ọmọ a má bẹ̀rẹ̀ gúnyán k’àdó gbèrìgbè mọ mọ̀
Ọmọ a yan eó meka run
Ọmọ a mẹ́ kìka kàn yan ẹsinsun t’ọrẹ
É e ṣojú un ríro, ìṣẹ̀dálẹ̀ rin ni
Ọmọ a mi malu ṣ’ọdún ìgbàgbọ́
Ọmọ elési a gbàrùnbọ̀ morun
Ọmọ elési a gbàdá mo yóko
Èsì li sunkún ètìtù kọ gbà àrán bora li Gèsan Ọba
Ọmọ Olígèsan òròrò bílẹ̀
Ọmọ alábùṣọrọ̀, a múṣu mọdi
Àbùṣọrọ̀ lu lé uṣu, mọ́ m’ẹ́ùrà kàn kàn dé bẹ̀
Kare o ‘Lúàmi, ku ọdún oni o, è í ra ṣàṣe mọ ri a (Àṣẹ)

 

English Version

Continue after the page break

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti