Home / News From Nigeria / Breaking News / Orunmila The Owner Of The Spiritual Rope Of Ife That Connected All The Deities(àjoní Okun Ife).
orunmila

Orunmila The Owner Of The Spiritual Rope Of Ife That Connected All The Deities(àjoní Okun Ife).

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, mo gbaladura laaro yi bi a se njade lo wipe eledumare yio da abo re to nipon to si gboro bowa o ase.
Laaro yi mo fe ki eyin eniyan mi mo wipe gbogbo nkan ti a nse ninu aye loni naa lo ti sele nigbakan ri, gbogbo igbese ti onikaluku wa ngbe ni awon irunmole naa ti gberi seyin nigbati won wa nile aye.
Nigbati awon irunmole yi nbo, eledumare gbe ÀJONÍ okun ife sile, o si sope eniti o ba maa je Olori won ni yio gbe ÀJONÍ okun ife dani, gbogbo omo irunmole ni won njijadu ki won le gbe ÀJONÍ funwon sugbon gbogbo agbara won lati le gba pabo lo jasi, eledumare si gbe ÀJONÍ yi fun Orunmila wipe oun ni ko gbe dani gegebi eniti o ni imo to ye kooro to si le dari ohunkohun pelu ogbon ati imo re, eleyi lo fi je wipe a ri Orunmila gegebi Olori awon irunmole ti won ro wa saye.
E jeki a gbo nkan ti odu mimo OGBEMOSUN so:
Orunmila ni won sebinu erin won fi di osán
Won sebinu ijakisan won yo iwo re
Won sebinu òdú pàpàràpà won gbe idé somi ÀJONÍ ni okun ife, Ogun ndu lati gbe dani, ija, obalufon, sango, osanyin, osun, Oosa nla, Oosa ogbe, Oosa òbà, Oosa akoko ati gbogbo omo irunmole patapata ni won ndu ÀJONÍ okun ife lati gbe dani sugbon Orunmila ni eledumare gbefun gegebi eni ti o ni imo ati òye pupo tayo ju ti awon akegbe re lo, sugbon eleyi wa fa ibinu ati ilara lopolopo laarin awon omo irunmole, bi awon omo irunmole se padi apo po pelu osanyin niyen lati ki won le ji ÀJONÍ okun ife gbe nile Orunmila ki won le raye pa Orunmila ati lati gba ipo olori ti eledumare fisi lowo re, osanyin de wa je aburo si Orunmila to je wipe ko sibiti Orunmila nparamo si ti ko mo debi ibiti Orunmila ngbe ÀJONÍ okun ife si pamo, bi awon omo irunmole se se ipade laarin ara won niyen ti won sope ki osanyin lo ji ÀJONÍ okun ife gbe nile Orunmila, bi osanyin se gbe ÀJONÍ se lo lo rimole sidi esu to wa niwaju ile Orunmila, nigbati o wa di ojo àjo seni Orunmila lo sibi to gbe ÀJONÍ okun ife si ko maa mura àjo sile sugbon iyalenu lo je wipe Orunmila ko ri ajoni okun ife mo nibe, eniti ÀJONÍ yi ba si wa lowo re sugbon ti kori mo seni awon omo irunmole maa pa, bi eru se ba Orunmila niyen, se lo wa bi oke iponri re leere wipe kini nkan toun maa se to je wipe ti oun ba ti e wa ku ti gbogbo nkan ile oun koni baje, won wa ni ko lo rubo, igba ibete ki o lo gbe sidi esu niwaju ile re Orunmila si rubo, bi Orunmila se gbebo sidi esu seni aja de to bere sini nje ìbètè yen gidi gan gbogbo ibiti ìbètè naa dasi seni aja fi owo re mejeeji wa gbogbo ile ibe se lo gbe ÀJONÍ jade sita, gegebi atimo wipe arubosobo ni won nse nigba kutu iwase, nigba to se die seni Orunmila gbera lati lo wo ibi to gbe etutu si nigba to maa debe, seni Orunmila ba ÀJONÍ okun ife nile ti yepe ti bo inu Orunmila dun lo ba si mu o dile nigbati Orunmila dele o mu ose dudu ati funfun selo fi fo ÀJONÍ okun ife to mo daadaa o wa gbe sorun o nlo si àjo, ki Orunmila to de àjo awon omo irunmole ti nso orisirisi òrò wipe Orunmila yen oni la maa pa bi ko bati gbe ÀJONÍ sorun wa si àjo sugbon nigbati Orunmila maa wole pelu ÀJONÍ okun ife saarin won enu ya gbogbo won, won si se àjo Orunmila lo sile re awon omo irunmole toku ba perawon jo won bere sini nbu osanyin wipe ko sise ti won ran pe se lo nparo funwon, sugbon osanyin fi yewon wipe oun gbe ÀJONÍ sugbon o ya oun lenu bi Orunmila se ri, o si fi won lokan bale wipe oun yio pada lo gbe, lotito osanyin lo gbe ÀJONÍ okun ife pada o si lo rimole sori akitan, nigba to di ojo àjo miran Orunmila tun lo sibi to gbe

 
ajoni si sugbon ko tun ri nibe bi eru se ba Orunmila niyen, o tunlo bi oke iponri re leere nkan toun maa se to je wipe ti oun ba ti e wa ku nigbayi ti gbogbo nkan ile oun koni baje, won wa ni ko lo rubo, eru eko, eru akara ati opolopo ere funfun ki o lo gbe sori akitan Orunmila si rubo, bi Orunmila se gbebo sori akitan seni awon elede de ti won bere sini nje awon nkan yen, Orunmila ba ni koun gbonse koun to ma lo sile, ki o to se tan awon elede ti je gbogbo nkan etutu yen gbogbo ibiti awon ere yen dasi seni elede fi imun wu gbogbo ile ibe se lo gbe ÀJONÍ jade sita, nigbati Orunmila maa gbonse tan selo sope koun wo ibiti oun gbe etutu si nigba to maa debe, Orunmila ri wipe awon elede ti je etutu naa ese toni koun gbe siwaju seni Orunmila nwo ÀJONÍ okun ife nile ti idoti ti yi lara inu Orunmila dun lo ba gbe ÀJONÍ o dile nigbati Orunmila dele o mu ose dudu ati funfun selo fi fo ÀJONÍ okun ife to mo daadaa o wa gbe sorun to nlo si àjo, ki Orunmila to de àjo awon omo irunmole ti nso òrò wipe Orunmila yen oni la maa pa bi ko bati gbe ÀJONÍ sorun wa si àjo sugbon nigbati Orunmila maa wole pelu ÀJONÍ okun ife lorun enu tu ya gbogbo won, won si se àjo Orunmila lo sile re awon omo irunmole toku ba tun perawon jo won bere sini nbu osanyin wipe oniro ni won ni ko sise ti won ran pe se lo nparo funwon, sugbon osanyin fi yewon wipe oun gbe ÀJONÍ sugbon o ya oun lenu bi Orunmila se tun ri yi, o si fi dawon loju wipe igba keta ajeijetan ni yi oni oun yio pada lo gbe ÀJONÍ ti Orunmila ko sini foju kan mo layelaye, lotito osanyin lo gbe ÀJONÍ okun ife pada o si lo gbe ju sinu omi bi ÀJONÍ se wo inu Omi seni onirangbankangban eja aro gbeje, nigba to tun di ojo àjo miran seni
Orunmila tun lo sibi to gbe ajoni si sugbon ko tun ri nibe bi eru se ba Orunmila niyen, Orunmila ni kosi aniani eleyi loun maa fi ku lowo awon omo irunmole, bi o se tunlo bi oke iponri re leere nipa nkan toun maa se to je wipe ti oun ba ti e wa ku nigbayi ti gbogbo nkan ile oun koni ku, won wa ni ko lo bo ori re pelu obi meji ati eja aro tutu elegbaafa won ni sugbon Orunmila ko gbudo naa eja naa ti won bati da owo le o Orunmila loun gbo, bi Orunmila se gbera niyen to lo sodo nibiti awon apeja ti npeja o si ba awon odo kunrin kekere meji ti won nfi ìkó sinu Omi bi ìkó won se gbe eja seni Orunmila ran won lowo lati gbe eja naa sita igba yen ni Orunmila loun maa ra eja naa sugbon awon omode kunrin naa ni awon ko ta eja won nitori inakuna ni Orunmila maa naa, Orunmila wa bewon wipe oun yio ra daadaa, bi won se ta eja fun Orunmila ni egbaafa niyen Orunmila ba se omun tele o gbeja si nigba to dele o bo ori re o si dobe le eja lofun sugbon Orunmila ri wipe nkan wa lofun eja naa to ha enu obe bi baba se kowo sofun eja naa niyen nigba to maa fa nkan naa jade se lo se ÀJONÍ okun ife ti osanyin lo ju sinu Omi, inu Orunmila dun o we lose dudu ati funfun o sigbe ÀJONÍ korun o kori si àjo Omo irunmole Orunmila wa wole pelu ÀJONÍ okun ife lorun enu tu ya won, won woju ara won yin-yin-yin, Orunmila ni beeni; Oni won sebinu erin won fi di osan
Won sebinu ijakinsan won yo iwo re
Won sebinu òdù pàpàràpà won gbe idè somi, ÀJONÍ ni okun ife, Orunmila ni beeni oun ti ri Ogun lakaye fo dide nibi to joko si o Kunle siwaju Orunmila ò kàn pá nigba kinni, o kan nigba keji o tun kan nigba keta o loun fi agba fun Orunmila.
Ojo naa ni awon omo irunmole ko wa ri ÀJONÍ gba lowo Orunmila, baba wa njo o nyo o nyin awo awon babalawo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru arukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami larusegun arusegun ni a nbawo lese obarisa.
Orunmila wa fiyere ohun bonu wipe:
Olóhun ma rohun e àwàkúrú mòjeje o awa
Olóhun ma gbohun e àwàkúrú mòjeje o awa
Mo ba Omi dore
Mo ba omuwe doluku
Koma seni to mo wipe inu Omi laagborin eja o àwàkúrú mòjeje o awa.
Orunmila ni beeni o loun ri nkan oun seni gbogbo omo irunmole tuka gbuu, bi ÀJONÍ okun ife sedi ti Orunmila niyen o.
Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe gbogbo awon eni ibi ti won nfoju sowa kiri ti a ko mo eledumare yio bu ifoju luwon, eledumare a tu asiri awon odale ore funwa o, ole ara ati ole emin koni jawa o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO

 

 

ENGLISH VERSION:

Good morning my people, how was your night? Hope it was really great, I pray as we are going out this morning may God cover us with his strong shelter.
This morning I want you people to know that we are following the steps that deities took while on earth. Individual deity also fought for the post of leadership among themselves while on earth as we human beings are also doing this day.
But fortunately Orunmila was fortunate to be the leader of all deities because he is the one that holds the spiritual rope of ife(ajoni okun ife) that connected them.
Let’s hear the clarification from the holy corpus of OGBEMOSUN:
Orunmila ni won sebinu erin won fi di osan
Won sebinu ijakinsan won yo iwo re
Won sebinu òdù paparapa won gbe idè somi, ÀJONÍ is the rope of ife, this spiritual neck rope was given by God to all deities but he gave it to Orunmila as a leader that can hold it because he is the one that knows both front and back of the earth, and full of wisdom, but all other deities were trying to collect the ÀJONÍ from Orunmila, Ogun lakaye tried his best possible but it prove abortive, sango, oya, osun, ija, Oosa nla, Oosa oko, Oosa ogbe, Oosa akoko, and others but none of them succeeded, after this, all deities planned to steal ÀJONÍ rope from Orunmila so that they can punish him and remove him from the post of leadership, and out of the deities osanyin was said to be the younger brother to Orunmila, he knows everything about Orunmila and he is the only person that knew where Orunmila kept ÀJONÍ rope, all deities planned with osanyin to go and steal ÀJONÍ rope and osanyin went into the room of Orunmila and took ÀJONÍ rope and he went to buried it beside esu icon in the front of Orunmila’s house, and it is compulsory that Orunmila should put on this ÀJONÍ rope on his neck whenever they have meeting for all deities to see that is not missing, when it is the meeting day, Orunmila went to where he kept ÀJONÍ rope to take it to prepare for meeting but he found nothing there, Orunmila was confused and scared because all other deities will kill him if he didn’t bring ÀJONÍ rope to the meeting, so he just summoned courage to cast his divination so that if deities kill him but his households will be living fine and his divination advised him to offer a calabash of “ìbètè and he should place it beside the esu icon in the front of his house and he complied, when dog reached there it just started eating and this dog poured the ibete on the ground, and was eating it seriously and this dog started using his hands to digging where the sacrifice was placed and fortunately this dog brought ÀJONÍ out of the ground, as we know that it is good to check whether our sacrifices was accepted after a while that we placed it down, Orunmila decided in the evening time to check whether the sacrifice was accepted so when he reached there he just found the ÀJONÍ on the ground and its body was full of dust, Orunmila was very happy he took it and washed it with local soap, when it is meeting time he put it on his neck and he was heading to meeting of deities, before he arrived all deities have been murmuring the way they will maltreat Orunmila if he can’t provide out the ÀJONÍ rope, so when Orunmila entered there they were shocked because they all believe that Orunmila will never get where osanyin buried it, they did their meeting and Orunmila went away, other deities called themselves together and abusing osanyin that he lied to them that he buried down ÀJONÍ rope but osanyin claimed he did not lied but don’t just know how Orunmila found it, and he promised them again that he will know another step to take, osanyin went again to Orunmila’s house and stole ÀJONÍ rope and he went to buried it on the dunghill, when it is a day of meeting Orunmila went to take ÀJONÍ rope so that he can be preparing for meeting but ÀJONÍ was again disappeared, and Orunmila was very sad and he said there is no way he can escape death today, then he consulted his divination on what he would do so that if he die all his households will be living fine and he was advised to offer sacrifice, corncake, cake beans and white beans and he complied, he was told to placed it on the dunghill and he did so, but before he leaved Orunmila was said to deficate and after he was done he also decided to check what is going on from where he placed sacrifice, when he got there he saw that pigs have ate all the items and they dung everywhere with their nose, when Orunmila wanted to shift his leg his eyes focused on the ground and he saw ÀJONÍ rope Orunmila was shocked because he was confesed on what is happening, he took ÀJONÍ home and washed it with local soap, when the meeting time reached he put it on his neck, and before he get to meeting all deities have been discussing on how they will maltreat Orunmila, when Orunmila entered with ÀJONÍ rope they were surprised, after the meeting Orunmila went home and other deities also met and shifted blame on osanyin that he is a great lair, that he was deceiving them of stolen the ÀJONÍ rope but osanyin told them that he took it but he was confused on how Orunmila use to get it and he promised that he will finish it all in the third time, when osanyin stole the ÀJONÍ rope in the third time he thrown it inside a big river and a big fish swallowed it, when it is a meeting day Orunmila went to take ÀJONÍ rope in order to prepare himself down but ÀJONÍ rope has also missed, Orunmila swept down immediately because he thought that there is nothing he can do to see ÀJONÍ rope, he consulted his divination that when he die today his households will never die too, and his divination advised him to go and feed his head with two kola nuts and fresh cat fish but he was warned not to reduce the amount they might called the fish, then Orunmila went to river where fishermen use to catch fish and he saw two young boys fishing and he assisted them to bring out the fish, fortunately it was big cat fish and he bought it from them without reducing the amount they sold it, when he reached home he fed his head and prayed to his households that nothing should affect them after he demise, when he finished, he slaughted the fish on the neck and he noticed that something is cracking the mouth of the knife and he decided to put his finger inside, as he put finger, his finger touched something when he will drawn it out fortunately it is ÀJONÍ rope, Orunmila was greatly happy and he use local soap to wash it, when it is the meeting time Orunmila put it on his neck, before he arrived at meeting all the deities have been hurl abusive words on him, they have been plan on how they will executed him, not long Orunmila entered and they saw ÀJONÍ rope on his neck shining like gold, they looked at their faces, Orunmila said yes;

 

They were aggrieved of elephant it was used as rubber
They were aggrieved of ijakisan they removed its horns
They were aggrieved of òdù pàpàràpà they threw idè inside the river
ÀJONÍ is the connected rope of ifè, Orunmila said yes he found it, Ogun lakaye stood up and he kneeled in front of Orunmila he bowl for him three times and Ogun said he accepted you as their leaders.
That is how ÀJONÍ became Orunmila’s property and he didn’t lose the post of leadership, he was dancing and rejoicing praising priest the priests were praising ifa while ifa was praising God.
He started singing the song of ifa that:
The owner has seen his property
Àwàkúrú mòjeje o awa
I became friend with water
Àwàkúrú mòjeje o awa
I became friend with swimmers
Àwàkúrú mòjeje o awa
Nobody knows that it is inside water they dropped idè
Àwàkúrú mòjeje o awa.
My people, I pray this morning that whosoever that is monitoring our movement will be blind folded, God will reveal the secret of our enemies to us and we shall never experience the operation of thief in our lives amen.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

taniolohun

Esin Ajeji Pelu Ete