Leyin rogbodiyan to be sile ni agbegbe Mile 12 to wa niluu Eko l’Ojobo ose to koja yii (03/03/16), okunrin kan ti oruko re n je Daniel Igba lo ti ke gbajari sita wi pe, awon kan ja omo gba lowo oun nigba ti wahala naa gbena kari. Ninu itaporogan to waye laaarin eya awon Hausa inu oja Mile 12 ati awon Yoruba ni Ogbeni Igba ti gbe padanu omo re, eni odun kan ati osu meje ti ko si le so pato ibi ti omo na wa bayii.
“Ile ni mo wa ni nnkan bi ago mewaa aaro nigba ti wahala naa wo inu adugbo wa. Mo sare gbe omo mi lati sawo ile lo. Sugbon bi mo se n salo ni awon eniyan naa sare tele mi leyin, won lemi ba, won si bere si ni na mi. Won fi ake sami lori ati lowo. Ni akoko yii, mo si gbe omo mi mora sibe naa. Bi mo se ni ki n tun dide ki n maa salo ni mo subu. Bayii ni won se ri omo naa jagba lowo mi. Lati igba naa, a ko ti ri omo wa. Iya re ko si nile ni akoko naa, o lo si ileewe,” Ogbeni Igba se alaye naa bee.
Ninu ija nla to waye yii ni aimoye emi ati dukia ti gbe sofo ko to di wi pe awon omo ologun ile wa to wa dawo rogbodiyan naa duro.