Sanwo-olu dáhùn ìbéèrè okada ló̩wó̩ aké̩kò̩ó̩ Chrisland
Láti o̩wó̩ Yínká Àlàbí
Gomina Babajide Sanwo-olu ti ipinle Eko lo n dahun orisiirisii ibeere lowo awon akekoo ile-iwe Chrisland to wa ni ilu Opebi ni Eko, nigba ti o gba won lalejo ni oni ojo kokanlelogbon, osu kin-in-ni odun yii.
Gomina ni ilekun oun si sile fun omode ati agba. Gbogbo ibeere awon akekoo yii pata ni gomina dahun. Eyi ti o ya gbogbo eniyan lenu ni ofiisi gomina naa ni ibeere nipa okada ati keke elese meta ti won ko ni sise mo lati ola ojo kin-in-ni osu keji.
Gomina ni ijoba oun ko lo tile bere ofin naa. O ni ofin yii ti wa lati odun to ti pe. O ni ju gbogbo re lo, ijoba ibile ati ijoba idagbasoke meedogun ni awon keke ati okada ko ti ni sise. O ni aaye gba won bi won ba se fe ni awon ijoba ibile ati ti idagbasoke mejilelogbon to ku.