Bi o tile je wi pe iriri odun metadinlogbon (27) ni Ogbeni Issa Hayatou ti ni nipa didari ajo to n ri si ere boolu ile Afirika, Confederation of Africa Football.
Sibesibe awon ololufe ere boolu ni awon ilu okeere ko sai maa kominu nipa boya agbara re le tuko ipo re tuntun gege bi adari ajo ti n ri si ere boolu agbaye, FIFA.
Hayatou ni won ti kede re gege bi Aare-fidi-he ajo FIFA latari asemase Ogbeni Sepp Blatter, eni odun mokandinlogorin (79), to ti n tuko ajo naa wa lati nnkan bi odun metadinlogun (17) seyin.
Blatter ni won ni ko lo rokun nile fun odindi aadorun (90) ojo lati fi se iwadii awon esun jegudujera ti won fi kan-an.
Awon aheso ti n ja lawon ilu okeere yii ni Hayatou, eni odun mokandinlaadorin (69), ti ko lati soro ba nigba to wo inu ofiisi re tuntun lo to wa ni Zurich l’Ojobo ose to ko ja yii.
Hayatou to je omo ilu Cameroon lati ile alawo dudu so wi pe,” Ipo ti a ba ara wa gege bi ajo FIFA je ohun ti a ko pinnu re tele, sugbon a ni lati tesiwaju lai siye meji”.
Orisun: Olayemioniroyin.com