Seyi Makinde, mo gbà fún ọ lórí ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tó o ṣe ní ìpínlẹ̀ Oyo—Yemi Ọṣinbajo
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ṣe wọ́n ní yini yini kí ẹni le sèmí ì ,bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ rí,nígbà tí
Igbákejì Ààrẹ ilẹ wa, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo gbósùba mo gba fun ọ, fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ, Onímọ̀ ẹrọ Seyi Makinde lórí Ìlànà ẹkọ ọfẹ tó gbé kalẹ̀ nipinlẹ Ọyọ.
Àtẹ̀jáde kan tí akọwe Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ fétò Ìròyìn, Taiwo Adisa fisíta ṣàlàyé pé, igbákejì Ààrẹ gbósùba bẹẹ fún Seyi Makinde lásìkò tí wọ́n jọ péjú síbi ìsìn ayẹyẹ ọgbọn ọdun tí wọ́n dá Ìjọ Bishop Taiwo Adelakun, Victory Church sílẹ̀ nílù ú Ibadan.
Osinbajo ṣàlàyé pé inu oun dun bí Gómìnà Makinde ṣe tẹwọgba ìpèníjà tó wà nídìí ìpèsè ẹkọ ọfẹ to tun jẹ ojúlówó nipinlẹ Ọyọ.
Osinbajo fikún ún pé Ìjọba Muhammadu Buhari gan sọ logunjọ osu Kẹfa ọdun 2019 pé ètò ẹ̀kọ́ yóò jẹ́ ọfẹ yika orílẹ̀èdè Nàìjíríà fún ọdún mẹsan àkọ́kọ́ nile ẹkọ alakọbẹrẹ àti girama, t’íjọba àpapọ̀ kò si lee kan nipa fawọn ijọba ipinlẹ láti se bẹẹ.
Ó wá jẹjẹ pé Ìjọba àpapọ̀ yóò ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìpínlẹ̀ láti se amusẹ ìpèsè ojúlówó ẹkọ ọfẹ pẹ̀lú afikun pe Ìjọba yoo ran wọn lọwọ ni gbogbo ọna lati ri daju pe afojusun ìpèsè ojúlówó ẹkọ ọfẹ, tó tún jẹ dandan di ohun.
Nigba to n fesi, gomina Seyi Makinde ni ẹkọ ọfẹ ti di ohun nipinlẹ Ọyọ nítorí Ìlànà ètò ẹ̀kọ́ nikan ni ọ̀nà tó daju láti mu adinku ba ìṣẹ́ àti osi ati Ìlànà ìrónilágbára tó pegedé jùlọ fáwọn ọdọ.
“Lóòótọ́ ọdún mẹrin kò tó láti gbé wa dé ibi tí a ń lọ à mọ́ ọdún mẹrin tó láti fi ìpìlẹ̀ gidi lélẹ fún ètò ẹ̀kọ́, èyí tí Ìjọba tó ń bo yóò mọ le lórí.”
“Ọpọ àwọn asaájú wa ló sì ń ròyìn èrè ẹkọ́ ọfẹ Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ tí wọ́n jẹ anfaani rẹ̀ bí ó tilẹ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ tí Awolọwọ ti papoda. Ṣùgbọ́n ipa ẹkọ ọfẹ ti Awolọwọ fi sílẹ̀ ló jẹ́ òpó t’íjọba mi fẹyinti ní ìpínlẹ̀ pinlẹ Ọyọ.”