Soworẹ́ gbòmìnira láhàmọ́ ọ́ DSS pẹ̀lú ọgọ́rùn ún mílíọ̀nù náírà
Fẹ́mi Akínṣọlá
Èèyàn téégún ń lé,kó máa rọ́jú,bó ṣe ń rẹ ará ayé,náà ló ń rèrò ọ̀run. Àgbálọ gbábọ̀, ilé ẹjọ́ gíga t’ìjọba àpapọ̀ l’Abuja ti gba béèlì Omoyele Soworẹ́ to ṣagbatẹru iwọde “Revolution Now”.
Ọgọrun un miliọnu náírà ni ilé ẹjọ́ fi fun Soworẹ́ ni béèlì pẹlu oniduro meji lọsan ọjọ Ẹti.
Soworẹ́ ti wa ni ahamọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS lati ọjọ kẹta oṣu Kẹjọ ọdun yii lẹyin ti wọn mu un niluu Eko.
Adajọ Ijeoma Ojukwu paṣẹ fun Soworẹ́ pe ko gbọdọ rinrin ajo kuro l’Abuja.
Ẹwẹ ileẹjọ kan ti kọkọ paṣẹ pe ki ajọ DSS fi Sowore silẹ latimọle wọn pẹlu akẹgbẹ rẹ, Olawale Bakare, ṣugbọn ajọ DSS kọ lati tẹle aṣẹ ileẹjọ.
Aadọta miliọnu naira ni ile ẹjọ fi gba béèli Bakare lẹyin ti wọn fi ẹsun onikoko meje kan wọn ninu eyi ti ifipa doju ijọba bolẹ wa ninu rẹ.
Adajọ Ojukwu ni kosi idi kan to le mu ki ileẹjọ ma fun Soworẹ́ ati Bakare ni béèli.
Ṣùgbọ́n, adajọ kilọ fun Soworẹ́ pe ko gbọdọ ba awọn Akọ̀ròyìn sọrọ lẹyin béèli rẹ.