Home / News From Nigeria / Breaking News / Tani Obalufon Ati Kini Ojuse Re?
asa yoruba

Tani Obalufon Ati Kini Ojuse Re?

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, a si tun ku imura toni eledumare ninu aanu re koni jeki a we ninu agbara eje bi a se njade lo loni o ase.
Laaro yi mo fe se agbeyewo lori ibeere ore mi kan lori ero alatagba fesibuuku yi to beere wipe, tani obalufon ati kini ojuse re?
Ibeere yi je ibeere gidi pupo, obalufon je okan gbogi ninu awon irunmole ti won ti ikole orun ro wa sikole aye, obalufon je orisa to pupa lopolopo, o je okan lara awon igbimo Ogun lakaye ati ìja o si je ode paraku sugbon oun ko nife si Omi rara nitori oun naa dabi orisa ina ni, o si je asegun bi ti Ogun lakaye naa.
Awon alaworo obalufon lokunrin ati olobinrin ki nfun ni Omi bi won ba nbo, obi, orogbo, Akuko adiye, emun ati opolopo epo pupa ni Obalufon feran lati maa je.
E jeki a gbo nkan ti odu mimo eji olosun so ninu oro re:
Owó bí owó
Esè bí esé
A difa fun obalufon lojo ti nlo ree bi ère lomo won ni ko karaale ebo ni ki o wa se, obi meji, orogbo, akuko adiye, emun ati opolopo epo pupa, o si kabomora o rubo won se sise ifa fun, lehin naa bi obalufon se bi ère lomo niyen o, o wa njo o nyo o nyin awo awon awo nyin ifa, ifa nyin eledumare oni riru ebo a maa gbeni eru atukesu a maa da ladaju nje ko pe ko jina ifa wa bami ni jebutu ire nje jebutu ire ni a nbawo lese obarisa.
Ti a ba da odu mimo yi fun eniti o ba nwa oko tabi iyawo, idi niyi ti ko gbudo fi fe eniyan pupa rofoto nitori ère lo maa fe ti ibasepo won kosi ni mu ayo ati idunnu dani, beeni won kosi ni jere ara won.  Eyin eniyan mi, mo gbaladura laaro yi wipe obalufon yio bawa segun elenini ile ati ode o, gbogbo awon ota ti won ba nwa isubu wa, obalufon yio bawa ja koriko hawon lenu o aaase

 

English Version:

Continue after the page break.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

balogun ilu yoruba

Remembering Famous Balogun (Generals) of Yoruba Land.

1) Balogun Oderinlo of Ibadan – Conquered the Fulanis in Osogbo.2) Balogun Ibikunle of Ibadan – defeated the treacherous Aare Ona Kakanfo Kurumi of Ijaye.3) Balogun Akere of Ibadan – died while fighting against the Ijesha army in the Kiriji war.4) Balogun Orowusi of Ibadan – defeated the Ijesha army.5) Balogun Ogunbona of Egba land – conquered the Dahomey army.6) Balogun Osungboekun of Ibadan – replaced Latoosa in the Ekiti Parapo/Kiriji war.7) Balogun Olasile of Ijaye – served and died ...