Home / News From Nigeria / Breaking News / Kereyale / Yale – Iwulo Ewe To Wa Ninu Aworan Yi
ewe karaleye

Kereyale / Yale – Iwulo Ewe To Wa Ninu Aworan Yi

 

Ekaaro eyin eniyan mi, aojiire bi? Aku ise ana o, oni a san wa sire gbogbo, bi odun yi se ntan lo akoni fi aisan pari re lase eledumare ase.
Laaro yi mo fe ki a mo iwulo ewe to wa ninu aworan yi, oruko ewe yi a maa je KEREYALE/YALE, gegebi e se ngbo lenu opolopo awon omo yoruba ti won ba nse adura wipe ajidede niti ewe kereyale, nje gbogbo awon ti won nso bee lo mo ewe yi?
Ewe yi wulo pupo ninu akose ifa lorisirisi odu, o maa n mu ki ara alaisan tete ya lori idubule aisan towa, o maa nfun alaisan ni okun ati agbara lati le ji dide ninu aare ara, ewe yi si tun dara gidi lati maa fi we ifa nitori ki ara ifa naa baa le ya gagaga.
E jeki a gbe odu mimo IDIGBE yewo nipa lilo ewe yi.
Ifa naa ki bayi wipe:
Orunmila ni ùjèùjè moni ùjuùju
Orunmila ni ùjèùjè ùjuùju lo se omo Ogun lakaye moju ana
Orunmila ni ùjèùjè moni ùjuùju
Orunmila ni ùjèùjè ùjuùju lo se omo ija moju ana
Orunmila ni ùjèùjè moni ùjuùju
Orunmila ni ùjèùjè ùjuùju lo se omo obalufon moju ana
Orunmila ni ùjèùjè moni ùjuùju
Orunmila ni ùjèùjè ùjuùju lo se omo olota nile ado, omo eriru lode owo, omo peepee lode asin ati omo egbeje ebora moju ana
Orunmila ni ùjèùjè moni ùjuùju
Orunmila ni ùjèùjè ùjuùju lo se akapo toun gan moju ana
Moni Orunmila kilode ti o fi nfo bi ede to fi nfo bi eyo?
Orunmila dami lohun wipe oun ko fo bi ede oun ko fo bi eyo bi ki nse akapo toun ti won da oun ifa fun wipe ara akapo yi ko da rara, wipe gbogbo ara akapo naa lo je kikida aisan, mo wani toba jebi ti ti akapo tire ni, moni kini oun to maa fise to fi maa segun aisan naa?
Orunmila ni ki o lo ni obi meji, agbebo adiye, ewe kereyale…………ki won ko awon ewe won yi tele inu ifa ki won si ko ikin ifa le lori ki won maa bo ifa naa, moni motiru moti bebo de mogun ijelu omo onimogun otanlerin omo ejiede lorun, Orunmila wa ni to bati di ojo Keji ki won ko oun ifa jade ninu eje ki won si fowo ra oun ifa lara, nigbati a wa se bee ti a nraa mora se lo fiyere ohun bonu wipe; seni ara oun ya sasasa 2*.
AKOSE IFA RE: Ao ko awon ewe wonyen tele inu awo ifa ao wa ko ikin ifa le lori ao bo ifa naa bee ao pa adiye yen le lori toba di aaro ojo Keji ao ra ifa naa mowo ao te sibi to mo ki ara re baa le gbe, ao wa ko awon ewe wonyen pelu eje ara re ao gun pelu ose dudu ao gbaye ifa naa si alaisan naa yio maa fi we.
Eyin eniyan mi, mogbaladura laaro yi wipe lenu iwonba toku ki odun yi pari ako ni fi aisan pari re lase eledumare, gbogbo awon ti won wa ninu idubule aisan ni eledumare yio mu lara da, ajogun buburu koni mo ona ile wa o aaaseee.
ABORU ABOYE OOO.

 

 

English Version:

Continue after the page break.

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

masoyinbo

#Masoyinbo Episode Fifty-One with ‪@yemieleshoboodanuru589‬ #Yoruba #learnyoruba #yorubaculture