Home / Art / Àṣà Oòduà / YORÙBÁ DÙÚN KÀÁÁÁ
onka ede yoruba

YORÙBÁ DÙÚN KÀÁÁÁ

A – Alaafia ni fun o.
B – Buburu kan ki yo o subu lu o.
D – Dugbedugbe ibanuje ko ni ja le o l’ori.
E – Ebi o ni pa o nibi ti odun yi ku si.
E – Ekun, ose ko ni je tire.
F – Funfun aye re ko ni d’ibaje.
G – Gunnugun ki ku l’ewe, wa d’agba d’arugbo.
GB – Gbogbo idawole re a y’ori si rere.
H – Hausa, Yoruba, Ibo, gbogbo eya ati eniyan kaakiri agbaye ni yo koju si o se o loore.
I – Iwaju, iwaju l’opa ebiti re yo ma re si.
J – Jijade re, wiwole re, o o nik’agbako.
K – Kukuru abi giga, osi ati ise ko ni je tire.
L – Loniloni wa r’aanu gba.
M- Monamona ati ara Eledumare yoo tu awon ota re ka.
N – Naira, Euro, Dollar,Pound, Yen, Yuan, gbogbo owo ati oro kaakiri agbaye pelu omo alalubarika ati alaafia yoo mu o l’ore, won o si fi ile re se ibugbe.
O – Ojurere ati aanu yoo ma to o leyin ni ojo aye re gbogbo.
O – Ojo ola re a dara.
P – Panpe aye o ni mu o t’omotomo.
R – Rere ni agogo aye re o ma lu n’igba gbogbo.
S – Suuru pelu itelorun ninu oro at’alaafia yoo ba o kale.
S – Sugbon ati abawon aye re ti poora loni.
T – T’omotomo, t’ebitebi, t’iletile o ni d’ero eyin.
U – “U” kii s’awati lede Ijesha; a o ni fi o s’awati laarin awon eniyan. Ulosiwaju (ilosiwaju), use rere, ati ubukun (ibunkun) yio je tire.
W – Wa ri ba ti se, wa r’ona gbe gba.
Y – Yara ibukun, ire, ati ayo ailopin loo ma ba e gbe titi ojo aye re……
ASE EDUMARE.

Iwo naa fi ranse si awon ololufe re.

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

masoyinbo

#Masoyinbo Episode Seventy-three: Exciting Game Show Teaching Yoruba language and Culture