Home / Art / Àṣà Oòduà / Ile ejo to gaju lo ni yoo pari idaju iku Reverend King
Reverend Chukwuemeka Ezeugo
Reverend Chukwuemeka Ezeugo

Ile ejo to gaju lo ni yoo pari idaju iku Reverend King

Ile ejo to gaju nile yii ti kede ojo kerindinlogbon osu keji odun ti n bo (26/02/15) gege bi ojo ti igbejo adari ijo Christian Praying Assembly, Reverend Chukwuemeka Ezeugo, ti gbogbo eniyan mo si Reverend King yoo ma waye.

Reverend King yii lo pe ejo ko-temi-lorun latari ejo iku ti ile ejo giga ti ipinle Eko da fun-un.

Ile ejo to gaju yii, nibi ti Onidaju Walter Onoghen ti n joko ni o ti sun igbejo naa siwaju nigba ti awon agbejoro fun igun mejeeji bere si ni gba oro naa bi eni gba igba oti, ti won si tun bere iyan jija niwaju adajo.

Olori eka idajo ati komisanna fun eto idajo ipinle Eko, Onidajo Adeniji Kazeem, eni to farahan ni ile ejo naa pelu Arabirin Idowu Alakija ro ile ejo naa lati da ipejo tuntun naa nu, ki won si tele idajo ile ejo giga ipinle eko eleyii to ni ki won yegi fun maanu naa.

Reverend King, eni to koko farahan nile ejo lojo kerindinlogbon osu kesan-an odun 2006 lori esun mefa to dale ipaniyan ati igbiyanju lati paniyan.

Ninu awijare re, okunrin naa ni oun ko jebi awon esun naa. Sibesibe, onidajo Joseph Oyewole ti n joko nile ejo giga ilu Eko to wa ni Ikeja da ejo iku fun un lojo kokanla osu kini odun 2007 lori esun ipaniyan okan ninu awon omo ijo re, Ann Uzoh.

Ninu esun ti ijoba ipinle Eko fi kan Reverend King lo n wi pe, okunrin naa da epo bentiro si ara awon eniyan marun-un kan. Lara awon eniyan naa si ni Uzoh to doloogbe lojo keji osu kejo odun 2006 wa latari isele to sele sii lati owo Reverend King .

Orisun

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

orisa

The World of the Yoruba Orisa