Iléeṣẹ́ DSS tú Sowore sílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ gbọọrọ ní àhámọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn òṣìṣẹ́ DSS gbé Soworẹ lásìkò tí ó fi ń léwájú ìwọ́de “Revolution now”.
Ìtúsílẹ̀ rẹ̀ ń wáyé lẹ́yìn tí ó ti lo ọjọ́ márùndíláàdóje ní hàhámọ́ àwọn DSS.
Onírúurú ìdájọ́ ló ti wáyé èyí tí àwọn Ilé ẹjọ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ní kí wọ́n fi sílẹ̀ ṣùgbọ́n tí àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ DSS kọ̀ jálẹ̀ pẹ̀lú onírúurú àwáwí.
Àmọ́sá ni ọjọbọ ni ileẹjọ miran tun pa aṣẹ ki iléeṣẹ́ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS ó tú u sílẹ̀ láàrin wákàtí mẹ́rìnlélógún
Ìrètí wà pé yóó tún farahàn ní Ilé ẹjọ́ ní ọjọ́ Ẹtì nítẹ̀síwájú ìgbẹ́jọ́ rẹ̀.
Ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹjọ ọdún 2019 ni àwọn agbófinró DSS lọ gbé Ọmọyẹle Soworẹ lórí ẹ̀sùn pé ó ń ṣagbátẹrù àwọn ìwọ́de “Revolution now” eléyìí tó ń bèèrè fún ìṣèjọba rere lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ní kẹfa oṣù Kọkànlá ni ọ̀gbẹ́ni Soworẹ kọ́kọ́ mú ìlérí béèli àkọ́kọ́ tí Ilé ẹjọ́ fún ṣẹ ṣùgbọ́n tí iléeṣẹ́ DSS kò túu sílẹ̀.
Ìgbésẹ̀ ìfisáhámọ́ Sowore ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àjọ ilẹ̀ òkèèrè àti ti Nàìjíríà pẹ̀lú láti kígbe sí Ìjọba àpapọ̀ láti bọ̀wọ̀ fún òfin ṣùgbọ́n tí iléeṣẹ́ DSS kùnà láti tú u sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àṣẹ ìṣaájú láti ilé ẹjọ́.
Bákan náà ni iléeṣẹ́ DSS tún dá Olawale Bakare náà sílẹ̀.
Àwọn méjéèjì yí ni Ìjọba àpapọ̀ ń fi ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ gbàjọba kàn.