Home / Art / Àṣà Oòduà / Ilé Ẹjọ́ Tó Ga Jù Dá Seyi Makinde Láre Gẹ́gẹ́ Bíi Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́
seyi makinde

Ilé Ẹjọ́ Tó Ga Jù Dá Seyi Makinde Láre Gẹ́gẹ́ Bíi Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Ilé ẹjọ́ tó ga jù dá Seyi Makinde láre gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọ́wọ́-lọ́wọ́ onímọ ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé tí di ọmọ oṣupa lé ẹ̀ ní kò gún,……bí Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti fi ìdí ìyànsipo Seyi Makinde, gẹ́gẹ́ bí i Gómìnà ìpínlẹ Ọ̀yọ́ mulẹ. Èyí papà á ló sẹ̀rí i ọrọ gómìnà náà ṣaájú pé ,”Ìjọba Ọyọ yàtọ̀ sí ti Ọṣun àbí Ekiti tí APC leè fi àṣẹ iléẹjọ́ lé dànù”

Èyí wáyé lẹ́yìn tí olùdíje fún ipò gómìnà nínú ẹgbẹ́ òsèlú APC, Adebayọ Adelabu pe ẹjọ́ nílé ẹjọ́ náà pé, kí wọ́n fagilé ìdájọ́ ìgbìmọ tó gbọ́ ẹ̀sùn tó ṣúyọ lórí ètò ìdìbò gómìnà, àti ìdájọ́ Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.

Àwọn méjéèjì ló dájọ́ pé Ṣèyí Makinde ni gómìnà tó wọlé nìpínlẹ̀ Ọyọ. Ajimọbi kí Seyi Makinde kú oríire .

Bákan náà ni ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà yóó jókòó lórí ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí olùdíje fún ipò gómìnà ìpínlẹ Ogun látinú ẹgbẹ́ òsèlú Allied People’s Movement, APM, Abdulkabir Adekunle Akinlade pè tako alátakò rẹ̀ láti inú ẹgbẹ́ òsèlú All Progressives Congress, APC, Dapọ Abiọdun.

Akinlade àti ẹgbẹ́ rẹ̀, APM, ń fẹ́ kí Ilé ẹjọ́ fagilé ìdájọ́ ìgbìmọ tó gbọ́ ẹ̀sùn tó ṣúyọ lórí ìdìbò náà, àti tí Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, tó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Dapọ Abiọdun ló wọlé.

Send Money To Nigeria Free

About ayangalu

x

Check Also

Oyo under siege as Fatai Aborode Killed by a Suspected Herdsmen on His Farmland

Wale Oyewale The Chief Executive Officer, Kunfayakun Green Treasures Limited, Fatai Aborode, has been reportedly killed by suspected herdsmen near his farm along Apodun village in Oyo State on Friday. It was gathered that Aborode, a politician and prominent farmer, was killed just as he was leaving his farm around 4pm in company with his manager on a motorbike. The manager (name not given), who was said to have escaped gunshots, reportedly ran for his life. A source, who gave ...