Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá ti ṣe àfihàn àwọn afurasí tó jí ìbejì Akeugbagold gbé ní ìlú Ìbàdàn
Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní, àṣẹgbé kan kò sí, àsepamọ́ ló wà.Ni báyìí, kélé òfin ti mú àwọn ọ̀daràn tó jí àwọn ìbejì Alhaji Taofẹẹq Akewugba Gold gbé.
Méje ni àwọn kọ̀lọ̀rànsí ọ̀daràn náà, ọkùnrin mẹ́fà àti obìnrin atẹ̀yìntọ̀ kan tí wọ́n gbà láti tọ́jú àwọn ìbejì ní gbogbo ọjọ́ mẹ́jọ tí wọ́n lò lákàtà àwọn ajínigbé.
Ohun ìyàlẹ́nu ni wí pé méjì nínú Yatọ si pe ọwọ tẹ wọn, miliọnu mẹta din ẹgbẹrun lọna igba Naira (2.8m), ni awọn afurasi naa sọ pe awọn naa owo ti wọn gba fun itusilẹ awọn ọmọ naa ku.
Miliọnu mẹẹrin Naira ni wọn gba.
ọ̀daràn náà ló sún mọ́ Bàbá ìbejì pẹkipẹki gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́, mílíọ̀nù mẹ́rin Náírà ni wọ́n gbà kí wọ́n tó jọwọ ẹmi àwọn ọmọ náà.
Kọmísánà Àjọ ọlọ́pàá nípìńlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣina Olukolu ló ṣe àfihàn àwọn ọ̀daràn náà lọjọ Ajé ní olú iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tó ń bẹ ní agbègbè Ẹlẹyẹle nílùú Ìbàdàn.
Yàtọ̀ sí pé ọwọ́ tẹ̀ wọ́n, mílíọ̀nù mẹ́ta dín ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba Náírà (2.8m), ni àwọn afurasí náà sọ pé àwọn ná owó tí wọ́n gbà fún ìtúsílẹ̀ àwọn ọmọ náà kù.
Mílíọ̀nù mẹ́rin Náírà ni wọ́n gbà.
Fẹ́mi Akínṣọlá