Igbákejì gómìnà Òǹdó Agboola Ajayi tilé APC bọ́sí yẹ̀wù PDP
Ó dà bíi pé , ẹ kú àtilé bọ́ọ́lé ló kù báyìí, tí àwa òlùdìbò yóó ma kí àwọn olóṣèlú wọ̀nyí lásìkò yìí, tí wọ́n kàn ń múwa ṣeré nínú ọpọlọ, yí bìrìpé láti inú ẹgbẹ́ kan sí ìkejì.
Ìròyìn mí-ìn tí a gbọ́ báyìí ni pé ìgbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, Agboola Ajayi ti fẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀ bọ́ sẹ́gbẹ́ PDP.
Akọ̀wé Ìròyìn fún Ọ̀gbẹ́ni Ajayi, Tope Okeowo ló fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀.
Okeowo ṣọ fún akọ̀ròyìn pé lọ́jọ́ Àìkú ni ìgbákejì Gómìnà Òǹdó kọ̀wé fipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Tijó ti ìlù ni àwọnn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP fi kí Ọ̀gbẹ́ni Ajayi káàbọ̀ sínú ẹgbẹ́ wọn.
Kó dà, àwọn èèkàn nínú ẹgbẹ́ PDP gbàdúrà fún un bí wọ́n ti fi káàdì ọmọ ẹgbẹ́ lé e lọ́wọ́.
Ẹ̀wẹ̀, Akọ̀wé Ìròyìn rẹ̀ sọ fún akọròyìn pé lọjọ Ajé ni Ọ̀gbẹ́ni Ajayi yóó báwọn akọ̀ròyìn ṣọ̀rọ̀ lórí ìdí tó fi kúrò nínú ẹgbẹ́ APC lọ sí PDP àti ìgbésẹ̀ tó kan fún un láti gbé.
Fẹ́mi Akínṣọlá