Home / Art / Àṣà Oòduà / Irawo Olorin Ti Won Yin Ni Bajinatu Lodun 2007 Ti Pe Omo Ogoji (40) Odun Lonii
2face

Irawo Olorin Ti Won Yin Ni Bajinatu Lodun 2007 Ti Pe Omo Ogoji (40) Odun Lonii


Osu kewaa odun 2007 ni awon afura si kan gege bi agbanipa bere si ni rojo ibon fun Innocent Idibia ni ibudoko Cele to wa loju ona masose Oshodi si Apapa to wa niluu Eko.

Sugbon gege bi Ayinla Omowura se so ninu orin re kan wi pe, ” ori ti o royin ogun ko ni ku…,” Edua oke pada ko 2baba yo lowo iku ojiji.

Awon oniroyin amuludun ile adulawo ko sai menu ba bi Olorun oba se da 2face lola nidi ise orin kiko. Pupo awon olorin igbalode ti won jo bere ise orin lo je wi pe aye ti gbagbe won lai se wi pe won ku, sugbon irawo “Baale of Nigeria” si wa sibe.

Bi eniyan ba fe se rikisi ni yoo daruko awon olorin taka-sufe marun-un ti won laamilaaka julo nile Naijeria lai daruko Innocent Ujah Idibia, eni ti a bi silu Jos lodun 1975.

Lara awon agbaoje olorin agbaye ti 2baba ti ba tayo orin ni R. Kelly, Beenie Man, Akon, Victor Uwaifo, Wyclef Jean T-Pain ati bee bee lo.

Lara awon nnkan to ba bobo naa ninu je ju lo naa ni bo se bi omo kaakiri fun orisirisi obirin eleyii ti ko ni anfaani lati ri gbogbo won leekanna ni gbogbo igba to ba ji laaro ni gbogbo ajo aye re.

“Mo ti n dagba, awon iwa ewe ti mo ti wu seyin si ti di dandan ko fi mi sile lo. O kan je wi pe pupo awon asise mi ni ko se e pare. Edun okan lo je fun mi, bakan naa ni igbe aye mi gbodo tesiwaju. Ohun atijo ti koja, iwaju mi ni mo n wo lati je baba gidi fun awon omo mi ati awokose rere fun awon to n bo leyin mi.” – 2baba.

Tuface pe omo ogoji odun lonii, adura mi ni wi pe ko pe laye ninu owo, ayo, idera, ifokanbale ati alaafia.

Orisun

About admin

VI

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Aya but not Iyawo is the original Yoruba word for wife.

Did you know that AYA, not IYAWO, is the Yoruba language’s original word for wife? These days, the latter is utilized more frequently than the former. I’ll explain how Iyawo came to be. Wura, the first child and daughter of the King of Iwo (a town in Yoruba), was in the process of picking a bride and had to decide which one would be best for her.Like Sango, Ogun, and other well-known male Orisa, Yoruba Orisa traveled to Iwo to ...