Home / Art / Àṣà Oòduà / #OGULUTU: Olaju ti so ogbon aye atijo di omugo patapata

#OGULUTU: Olaju ti so ogbon aye atijo di omugo patapata


E ku asiko yii eyin eniyan mi, ko to di wi pe n maa se alaye ara mi tabi abala Ogulutu to je tuntun to gori Iwe Iroyin Owuro.

E je n sare bi yin nipa oun ti won pe ni “olaju.”

Kini olaju? Olaju je iyipada igbe aye awon eniyan nipa ohun eelo, irori tabi bi won se n ronu, imo ati ibasepo won pelu awon eniyan awujo; eleyii to yato si ti aye igba iwase.

A tun le so wi pe olaju je wi wo inu aye otun lati inu aye atijo pelu igbagbo wi pe aye otun dara ju aye atijo lo.

Awon kan tun se alaye olaju gege bi irin ajo lati inu igbe aye kan bo sinu igbe aye mi-in, eleyii to n tesiwaju laiduro rara.

Ohun pataki kan tun wa nipa olaju to ye ko ye gbogbo wa. Ti awujo ba n yi pada, o di dandan ki awon eniyan inu re yii.

Nitori wi pe ayipada to de ba igbe aye awon eniyan gan-an lo mu ki awujo o maa yi pada.

Ti igba ba wa n yi pada, ti awon eniyan awujo ba ko lati yi pelu igba, dandan ni wi pe ikolura tabi isoro yoo waye ninu igbe aye awon eniyan awujo.

Ki alaye mi le ye yin, e je n gbe opele ewi mi sanle. Eleyii wa lara awon ewi ti mo ke nikete ti a n mura lati jade ile iwe:

“Aye laelae lomo mi roju kawe ko gboye nla.
To o ba gboye, ise n be ni sekite f’alakowe to de tai morun.
Boya leyin mo wi pe alakowe to de tai morun o rise mo.
N se ni gbogbo won fese e tale kiri.
Ebi won kuku ko,
Sebi ise ni o to nnkan, omi lo se bee po joka”.

Bi o tile je wi pe iwe se pataki, sugbon o ti ye ki oye ye opolopo wi pe iwe nikan o to mo lati di eniyan atata lawujo bi ti aye atijo.

Igba n yi pada, olaju ti wole de. Ise egberun eniyan ti di ise ti enikan soso le se pelu iranlowo ero igbalode. Bee iye awon eniyan n posi kaakira agbaye lojoojumo.

Oye yii gbodo ye wa, a si gbodo wa ni imurasile lati ba igba yi, ati lati dogba pelu olaju to wole de.

Ti a ba ko lati se bee, afaimo ki awo ma sun lebi.

Olayemi, ojo ti n ro ti o ti da ni, Edua oke nikan lo mo iye eni ti o pa. Mo n meye bo lapo, e ni dudu ni, e ni funfun ni. Eni a n gbe iyawo bo wa ba, awon agba ni kii gbe ori iganna woran.

Olayemi Olatilewa ni oruko mi, ogulutu oro to ba denu afefe dandan ni ko fon de gbogbo ilekile. Sultan Akoroyin kaabo!

E ma gbagbe, bi eniyan ba fe gbe igbe aye ode oni ko pegede, onitoun ni lati kogbon aye ode oni to je gidi. Bawo ni eniyan se le ko ogbon aye ode oni?

E pade mi lose to n bo lagbara Eledumare oba mi oke. Ire o!
Olayemi Olatilewa
www.olayemioniroyin.com

About admin

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti