Home / Art / Àṣà Oòduà / Otun Olubadan tile Ibadan ti dagbere faye
Oloye Omowale Kuye

Otun Olubadan tile Ibadan ti dagbere faye

Otun Olubadan ti ile Ibadan, to tun je okan pataki ninu awon agba oye ile Ibadan, Omowale Kuye, ti dagbere faye leni odun metadinlaadorun (87). Oloye yii la gbo wi pe o dake ninu ile re to wa ni agbegbe Ikolaba to wa niluu Ibadan ni nnkan bi ago meje abo ale Ojobo ose to koja yii. Titi di akoko ti a fi n ko iroyin yii, awon ebi oloye naa ko ti kede ohun to sokunfa isale naa.
Ojo kejidinlogun osu kewaa odun 1928 ni won bi Oloye Omowale Ajani Kuye. O si kaye gboye nipa eto oro-aje (Economics) ni University of London lodun 1963. University of Syracuse to wa ni ilu New York, Amerika lo ti gboye eleekeji. Leyin eyi lo tun lo ka nipa imo ofin ni Nigeria Law School lodun 1978.
Aimoye eka ile ise ijoba ni Oloye Omowale ti sise ko to wa di wi pe o feyinti lodun 1988.

About admin

VI

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Happy New Calendar Year!!! It is 10068 of the Oodua Yoruba Calendar-–-KỌ́JỌ́DÁ

The Yoruba traditional calendar, called Kọ́jọ́dá, starts the new year on June 3rd and ends on June 2nd the following year. It’s a lunar calendar with a 4-day week (each day honoring different Orisa), 7 weeks in a month, and 13 months in a year—so their year is 364 days long. The months and weeks are deeply tied to farming cycles, moon phases, and religious rituals.The traditional Yoruba week has four days. The four days that are dedicated to the ...