Home / Art / Àṣà Oòduà / Eeto Owe L’esin Oro 4

Eeto Owe L’esin Oro 4

Mo ki gbogbo wa kaabo si akotun eeto yin, eeto wa owe l’esin oro. Laakoko, mo dupe lowo Olodumare ti o funwa ni oore-ofe lati tun pade loni, leyin igba ti a dagbere fun eeto ni ose to koja. Moki kabiyesi olumoye ti ilumoye akoko, awon olori, moki awon oloye, gbogbo igbimo aafin ati awon omo’oba l’okunrin ati l’obinrin. Gegebi isee wa, lori eeto yii ni a o ti maa yannana awon owe ile wa lolokanojokan ti a o si maa fi ko ara wa le’eko. Ni bayii e je ki a kanlu agbaami eeto.

Owe ti a o koko gbe yewo loni loo bayii- TI OJU BA N SE IPIN, A MAA N YO FI HAN OJU NI.
Ti oju ba ni idoti, gbara ti a ba ti yoo tan loju, eyan a fe mo ohun gan-an to n daamu oju re, oju ni yoo fi han lati rii, eyi ni won fi n so wipe b’oju ba n se ipin, aa yo han oju ni. Eyi ni wipe bi oko ba gba eyan, oko naa la o fi gbe e lo si ile iwosan lati toju.
Itumo ijinle; bi eyan ba huwa ibaje kan, won a je ki iru eni bee mo ni kiakia.
Lilo re; ti enikan ba n se nkan ti ko bojumu lawujo, ti a wa n dalekun tabi ti a n je ko yee wipe nkan ti o n se yii kobujumu to, a le pa owe yii fun iru eni bee wipe, bi oju ba n se ipin, a n yoo han ni, ko le mon wipe nkan ti oun nse kodaa.

Owe keji fun toni loo bayii- IGI GOGORO MAA GUNMI L’OJU, LATI OKEERE NI A TIN N LOOO.
ti eyan ba ti ri igi ti o yo sonso to le gun l’oju, lati ookan ni eyan a ti maa yera fun tabi dooji (dodge) re. Eyan o le laju sile ki o ri igi to le se e lese lo’okan, ki o maa yera fun-un, lai se omugo eniyan.
Itumo ijinle; ti eeyan ba n huwa ibaje kan, a gbodo tete je ko mon ko le tete jawo, tori bi ara ile eni ba n nje kokoro to oo dara, ti a o wi fun-un, huruhere re ko ni je ka sun loru.
Lilo re; ti a ba sakiyesi wahala kan ti o seese ki o suyo, ti a wa tete fe wa ona abayo si irufe wahala naa ki o to bee sile ni a le pa owe yii.

Owe keta fun toni lo bayii- AIFI ELE KEBOOSI, NI AI R’ENI BANI JOO.
aifarabale ke boosi ni o je ko dun un jo.
Ti eyan ba wo aarin oja to n korin wipe “iboosi o, iboosi o, iboisi o iboisi o” ki o to mo oun to n sele, awon eero a ti bo o, ti won yoo si maa joo si orin naa paapa. Sugbon ti eyan ba wo aarin oja to ni, “iboooooooosi oooo” awon eyan a tuka lori ere ni, pentuka ni, oro yoo di bo o lo o ya funmi, ki oju maa ribi nii, gbogbo ara lo’ogun re…..ere asapajude nii.
Itumo ijinle; aifarabale, aifogbon se e, aini suuru lo faa, ko si ohun ti a fi suuru o le se, suuru le se okuta jinna, bi eyan ba farabale, bo ba pa eera, yio ri ifun re ko. Pele la n pa amukuru pele. Ohun a feso mu kii baje, ohun ti a ba fipa mu, koko ni le mo nii. Eni to ba ni suuru, ohun gbogbo lo ni.
Eyi tun tumo si wipe ohun gbogbo ti a ba fogbon inu se, ko ni mu inira lowo rara. Nitori yoruba bo, won ni ogbon inu l’ejo nlo.
Ti ija kan ba fe sele, ti enikan ti fi suuru gbe oro kale, tabi fi suuru beere oro lowo enikeji, ko le fa ija rara.
Lilo re; ti eyan ba wa ninu eewu nla ti o sin fe iranlowo awon eniyan, ti iru eni be ko wa fe fi ara bale, a le pa iru owe yii fun wipe, aifelekeeboosi, ni a i reni baani jo ooo.

Tooo, ni hain ni a o ti danu duro fun t’oni, e je ka tun pade lose tombo pelu ase Eledumare.
Gegebi a se mon wipe ile eko ati imo ni aafin ilumoye, aaye wa fun afikun, ayokuro tabi atunse lori eeto ti toni. Eyin eyan wa lori eeto, e funwa ni awon owe ti o se reegi pelu awon oowe ti a na si afefe yii, ki atokun fi mon wipe oowe naa yewa yeeke. E seun

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

orisa

The World of the Yoruba Orisa