Home / Art / Àṣà Oòduà / A o ni ri ogun aisan

A o ni ri ogun aisan

A o ni r’ogun aisan!
Ifa ni:
Pere ni tewe iyeye, aloye ni ti peregun;
Piri l’eye olongo n ji;
A kii b’okunrun eye lori ite;
Gege lowu alantakun n fuye;
Ota kii ku, ota kii run;
Koko lara ota n le;
Ojojo kii sokuta lale odo;
Aluti la n lu eru oko;
Aluti la n lu eru ada;
Ere kii ba eri wo;
Ko ba won wa kii ba won lo;
Ope kii ba igi oko wo’we;
Efun kii mu igun, edi kii mu alakan;
Ota t’ota pa ka sai segun ota fun wa!
Aase!
Ao ni ba won ku iku ajoku!
Edi, efun, asasi ko ni mu wa ati awon tiwa!
Aaaaaaaaaaaase.

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Iṣẹṣe Kọ́jọ́dá/calendar – Fún Oṣù Ẹ̀bìbí/May 2025.

TÍ OSU TITUN BÁ DÉ, ARÁYÉ MÁA Ń YỌ̀ MỌ́ NI, WỌN MÁA BÁ GBOGBO WA YỌ AYỌ̀ IRE NÍNÚ OSU TITUN YÍÌ, PẸ̀LÚ ÀṢẸ ELÉDÙMARÈ . 1. Ọbàtálá/Òrìṣà-ńlá, Ọbalúayé/Ṣàpọ̀nná, Ògìrìyàn, Egúngún, Ìyàmi Àjẹ́. 2. Ifá, Ọ̀rúnmìlà, Èṣù-Ọ̀dàrà, Orí, Odù, Ọ̀ṣun, Ajé-Olókun, Ọ̀sányìn, Kórì, Ẹgbẹ́. 3. Ògún, Ìja, Ọ̀ṣọ́ọ̀sì, Erinlẹ̀, Òrìṣà Oko. 4. Jàkùta/Ṣàngó, Ọya, Aganjú, Yemọja, Ìbejì, Nàná-Bùkúù. 5. Ọbàtálá/Òrìṣà-ńlá, Ọbalúayé/Ṣàpọ̀nná, Ògìrìyàn, Egúngún, Ìyàmi Àjẹ́. 6. Ifá, Ọ̀rúnmìlà, Èṣù-Ọ̀dàrà, Orí, Odù, Ọ̀ṣun, Ajé-Olókun, Ọ̀sányìn, Kórì, Ẹgbẹ́. 7. Ògún, Ìja, ...