Home / Art / Àṣà Oòduà / ÀWỌN JAGUNJAGUN WA

ÀWỌN JAGUNJAGUN WA

Ó yá,
Ẹ jẹ́ á sàm̀bátá àwọn jagunjagun wa.
Ẹ jẹ́ ká f’orin ọgbọ́n yẹ̀ wọ́n wò,
Ká mọ rírì isẹ́ wọn t’ó yakin.
Pàtàkì l’àwọn ológun lórílẹ̀-èdè yìí;
Ișẹ́ takuntakun ni wọ́n kúkú ń ṣe.
Mo kírà f’áwọn sójà káàfàtà.
T’ọ̀sán t’ààjìn n’ọ́n ń șișẹ́ ìlú.
Bẹ́ẹ̀ ni tẹ̀mítẹ̀mí ni wọ́n fi ń jagun.
Bá a bá gúnyán wọn tán,
Ká f’ewé bò ó ló tọ̀nà.
Géńdé tó tó géńdé ní í lọ s’ójú-ogun.
Okùnrin tó t’ọ́kùnrin ní ń șișẹ́ẹ sójà,
Ẹni ẹ bá rí ẹ bi.
Akọni ogun ni wọ́n;
Kútańtì ni wọ́n-ọ́n ṣe.
Ìbà ẹ̀yin arógunmásàá;
Ọmọ arógun-má-fìgbà-kan-șojo.
Mo gbé’dìí f’ẹ́yin arógunyọ̀șẹ̀șẹ̀ káàfàtà.
Bí wọ́n ti ń pa wọ́n tó;
Bẹ́ẹ̀ l’eegun wọn ń le kankan bí iwin.
Wọ́n ń pebi mọ́nú ń’torí Nàìjíríà;
Wọ́n ń fara gbọta nítorí àwọn ọmọ wa.
Síbẹ̀, Zambo Dàsúkì,
Àt’àwọn ajòdìjẹ̀sọ̀ bíi tiẹ̀,
Wọ́n f’owóo wọn dá wọn lára.
Wọ́n f’ohun-ìjà dùn wọ́n;
Wọ́n f’ẹ̀mí wọn șòfò púpọ̀.
Bí wọn ‘ò mú Dàsúkì láyé,
Olódùmarè á mú alákọruwo.
Òbìtà ènìyàn tó sọ omi ọkà d’omi ìwẹ̀.
Ká sọ ọ́ kó yé wa yéké.
Àìsí nǹkan-ìjà tó gúnmọ́,
Lokùnfà bí Boko Haram ṣe ń rí wọn pa.
Ohun ojúu wọn ń rí kèrémí kọ́.
Nítorí ìșọ̀kan Nàìjíríà.
Ojoojúmọ́ l’àwọn sójà ń kú.
Ẹgbẹ̀ta la tún pàdánù láìpẹ́ jọjọ;
Tí gbogbo ẹbí wọn șì ń șọ̀fọ̀.
Àláùrà bá wa forí jì wọ́n o.
Șíjú àánú wò wọ́n,
Gb’ójú nínú ișẹ́-ibii wọn.
Kẹ́ wọn, gẹ̀ wọ́n.
Jẹ́ kí wọn ó r’Álùjánnà wọ̀.
Àwọn sójà t’ó kù láyé,
Pàápàá àwọn t’ó wà lójú ogun.
Bẹ̀rẹ̀ lát’orí ìmùlẹ̀ mi Adérẹ̀mí.
Tó fi káríi wọn gbogbo pátá poo.
Ọba-òkè bá wa mú wọn padà wálé.
Kí wọn ó ṣẹ́gun àwọn oníjàádì.
Alóyúnmábíi ọmọ ọba Kétu.
Awàșẹẹ̀tùdànù l’awo Awùjalẹ̀.
Bí wọ́n bá nàbọn sí wọn,
Kò ní f’ọhùn òkè.
Ẹ ‘ò ní ṣe kòńgẹ́ àgbá.
Ẹ ‘ò ní kú’kú àpalàdọ̀ fáàbàdà.
Apáa Boko Haram ‘ò ní káa yín.
Nítorí apá awọ́nrínwọ́n kì í ká’gi oko.
Apá àtẹ́lẹsẹ̀ kì í ká’jú-ọ̀nà.
Magbẹ̀yìn magbẹ̀yìn l’àgbà Lédì ń ké.
Kẹ́ ẹ rẹ́yìn ogun ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn.

Àmín àṣẹ!

About Awoyemi Bamimore

VI

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

policeman

Ọ̀gbẹ́ni Olaoye déèdé pòórá nílé ìtura kan nílùú Akure

Fẹ́mi Akínṣọlá Ádùrá tí a máa ń ṣe ni pé kí á má rin àrin f’ẹsẹ̀sí.Mọ̀lẹ́bí ọkùnrin kan, Ògbẹ́ni Olaoye Olatunde, tó jẹ́ igbákejì ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ girama kan nílùú Ọwọ ti ké gbàjarè pé ọkùnrin náà di àwárítì lẹ́yìn tó lọ fún idanilẹkọ ní ilé ìtura Sunview nílùú Akure. Iyawo arakunrin naa salaye rẹ pe, ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹjọ, ọdun 2025, ni ọkọ rẹ dagbere pe ohun n lọ fun idanilekọ kan n’iluu Akure, eyi ti wọn ...