Home / Art / Àṣà Oòduà / Iba Eleiye
iba eleye

Iba Eleiye

Orunmila wi Awo tan.
Ifa mi Awo ku mi Bara Agbonmiregun.
Ifa ni nibo ni Awo ku si?
Mo ni o ku awon Ajagaruwa.
Mo ni o ku awon Alsgbede orun ko mero ileke.
Mo ni o ku Okoko sii wele. 
Ifa lo di obiri 
Mo ni o di apawoda se
Orunmila lo di Opere 
Ifa mo ni o di Ikin oloju merin.
Ani komode ma lo s’oko
Omode kekere lo s’oko
Omode kekere ba eyin Alagemo loko
Ani ki agbalagba mo lo s’odo
Agbalagba lo s’odo 
Agbalagba ba iseju akan lodo
Omode kekere ko goodo he eyin alagemo
Beeni awon agbalagba ko gbodo he iseju akan lodo. 
Beeni e se ti ti, ti e fi pa Oniroronjiro
Beeni e se ti ti , ti e fi pa Oniroronjiro
Beeni e se ti e fi pa Iparomonyan oju omi
Beeni e se ti e fi pa Aasemogamoga
Toun tidun yankanyankan lenu.
Bi Eleiye ba n binu 
E je ka be Eleiye lowe si Eleiye. 
Ki a be Ogun teere Erija 
Ki a be Rjemu loropoo
Ki a be Orisa Ogiyan 
Ki a bs Apakoloro ti n ba won gbere ara re dogbon Ikin.
Ki a be Ikin sakasaka 
Ki a be gbogbo won lowo s’eleiye.
Aje kii roro ko je erun
Aje kii roro ko jegbin 
Sebi koko puoa leewo aparo. 
Bi esisi ba subu a fi ida re rori. 
Bi Eleiye ba nbinu erukuku ni bee. 
Ifa ki o ba mi be awon ota mi Eleiye.
Ki won ma se dina mo mi.
Ki won ma se ba temi je taya tomo. 
Ki won o ma se da oro mi ru.
Ifa wa gbemi lake awon ota mi Elejye.

iba eleye

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

balogun ilu yoruba

Remembering Famous Balogun (Generals) of Yoruba Land.

1) Balogun Oderinlo of Ibadan – Conquered the Fulanis in Osogbo.2) Balogun Ibikunle of Ibadan – defeated the treacherous Aare Ona Kakanfo Kurumi of Ijaye.3) Balogun Akere of Ibadan – died while fighting against the Ijesha army in the Kiriji war.4) Balogun Orowusi of Ibadan – defeated the Ijesha army.5) Balogun Ogunbona of Egba land – conquered the Dahomey army.6) Balogun Osungboekun of Ibadan – replaced Latoosa in the Ekiti Parapo/Kiriji war.7) Balogun Olasile of Ijaye – served and died ...