Home / Art / Àṣà Oòduà / Gbọ́ ń táwọn èèkàn ìlú ṣọ lẹ́yìn Búrùjí Kashamu

Gbọ́ ń táwọn èèkàn ìlú ṣọ lẹ́yìn Búrùjí Kashamu

Gbọ́ ń táwọn èèkàn ìlú ṣọ lẹ́yìn Búrùjí Kashamu

Bí ọmọ èèyàn bá wá sílé ayé, ìgbàgbọ́ Yorùbá ní pérúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ wáyé wá nájà ni. Ènìyàn ò sáà lè tajà tán kò sùn sínú ọjà, àti pé n tí kóówá gbe wá sínú ayé fún títà kò papọ̀.


Ìbà Ọ̀jẹ́túndé Asòlẹ̀kẹ̀ Olorì alágbàáà àná tó sílẹ̀ bora. Ó ní èèyàn tó wáyé wá ta góòlù kò papọ̀ mọ́ tẹni wáyé wá ta ẹ̀kọ.
Ẹni o wá tẹ̀kọ ṣe é ṣe kó tètè sẹ́rí wálé, góòlù kò yá títà bí ẹ̀kọ.
Gbogbo àsamọ̀ yìí ló díá fún pé n tá a bá wá tá láyé ní yóó ṣọ bí ìrìnàjò yóó ṣe pẹ́ tó tàbí yá sí.

Kò sí nínú ìròyìn mọ̀ pé Kofi -19 ń soro bí agbọ́n láàrin àwọn èèkàn ọmọ bíbí Orílẹ̀ yìí tó lóókọ lóókì, ọ̀kan pàtàkì sí ní Buruji Kashamu ẹni tí a fi àkójọpọ̀ ìwòye àwọn èèyàn lẹ́yìn rẹ̀ sọ di ìròyìn.

Ṣé lọ́jọ́ a kú làá dère, èèyàn ò sunwọ̀n láàyè. Gbólóhùn yìí ló bi Onírúurú gbólóhùn tó ń fọhùn lẹ́yìn ikú èèkàn olóṣèlú n nì,Buruji Kashamu.
Ṣé gángan láyé pẹ̀lú ojú méjì, ìbí tó bá sì gbà kójú sí kóówá ní yóó ṣọ bí ìròrí rẹ̀ yóó ṣe lọ.

Bí àwọn ìlúmọ̀ọ́ká àti olókoòwò ṣe n dárò àgbà ọ̀jẹ̀ olóṣèlú náà ló fẹ́ ẹ̀ jẹ́ àrà ọ̀tọ̀.
Díẹ̀ lára àwọn tó ṣọ tinú wọn ni Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ Ẹbọra Owu.
Bàbá náà ṣọ̀rọ̀ ìkẹ́dùn pé olóògbé náà kú . Bẹ́ẹ̀ ló bó o lójú pé Buruji khasamu rí gbogbo àǹfààní òfin lò láti borí àwọn Onírúurú ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án nílẹ̀ yìí àti lókè okùn síbẹ̀ ikú ti wá mú un lọ.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, Dàpọ̀ Abíọ́dún ti sàpèjúwe Sẹ́nétọ̀ Búrùjí Kashamu gẹ́gẹ́ bí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ ọmọnìyàn.


Gómìnà ní bótilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kò jọ sí nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kan náà, síbẹ̀ òun mọ̀ pé Sẹ́nétọ̀ náà ti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ gidigidi.
Àgbà òṣèlú àti adarí ẹgbẹ́ APC nílẹ̀ yìí Olóyè Bola Ahmed Tinubu tí sàpèjúwe Sẹ́nétọ̀ Búrùjí Kashamu gẹ́gẹ́ bí olóṣèlú tó fẹ́ràn àwọn èèyàn rẹ̀ tó sì nífẹ̀ẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tó nígbàgbọ́ nínú rẹ̀.


Ó ní .
Bruce ni ọ̀rẹ́ wọlé wọde ni òun àti Kasamu kó tó jẹ́ Ọlọ́run nípè.
Ó ròyìn ẹ̀ pé èèyàn rere ni àti pé ikú olóògbé náà jẹ́ ìmọ̀lára fún òun.O gbàá ládùúrà pé kí Ọlọ́run fáànù gbàá.


Gómìnà t’ẹ́lẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Èkìtì, Ayodele Fayose náà wà lára àwọn tó kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn ọmọ Orílẹ̀ yìí àti ẹbí olóògbé.O ròyìn rẹ̀ pé ojúlówó olóṣèlú tó fẹ́ràn àwọn èèyàn ẹkùn rẹ̀ ni.


Ó ní ẹ̀dá kìí rìn kórí ó mọ́ mì, kò sééyan tí wọ́n wọ́n sí abíyá ẹ̀ sókè tí kò ní rùn. Èyí ló fi fèsì sí ọ̀rọ̀ tí Olóyè Olúṣẹ́gun Obasanjọ ṣọ lórí olóògbé Búrùjí Kashamu.
Bí ó ó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú olóògbé náà kò tẹ́yìn mọ́, síbẹ̀ ìtàn àṣesílẹ̀ n fọhùn lẹ́yìn olóògbé Búrùjí Kashamu.
Níwọ̀n ìgbà tí èèyàn tí kò tíì kú kò mọrú ikú tí yóó pa á, ẹ jẹ́ á gbìyànjú ká nítàn réré, ṣaájú ọjọ́ àtisùn un wa.

Fẹ́mi Akínṣọlá

http://iroyinowuro.com.ng/2020/08/10/gbo-n-tawon-eekan-ilu-%e1%b9%a3o-leyin-buruji-kashamu/

About ayangalu

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

History 101: What it takes to be a MENTALLY ENSLAVED FOOL in Your ancestral Land.

History 101: What it takes to be a MENTALLY ENSLAVED Harlequin in Your ancestral Land.

The quote for today is a page from Toyin Falola’s book, ‘Yoruba Warlords of the 19th Century’. To a lot of Yoruba Muslims. Islam means servitude to Usman Dan Fodio’s estate at Sokoto. They indulge in the same idiocy that led to the fall of the great Hausa civilization. Many Yoruba Muslims from Oyo are a dangerously brainwashed set of people that would pose future danger for the preservation of Yorubaland like their ancestors who pledged allegiance to Ilorin and ...