Ebenezer Obey ò kú o–Asojú ẹgbẹ́ Obey
Ó dà bí ẹni pé àwọn èèyàn kìí fẹ́ rán aṣọ wọn níbi tó gbé ya mọ́ lóde òní. Ìtọ pinpin àti àríwísí ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀ ló kù tí wọ́n ń mójútó, bọ̀kílẹ̀ èyí sì ń dá ìṣòro tó pọ̀ sí àwùjọ, dípò o kí ó mú ìlọsíwájú báwa.
Irúfẹ́ àwọn àhesọ ọ̀rọ̀ yìí ló mú kí aṣojú ẹgbẹ́ orin bàbá Ebenezer Obey, Túnjí Ọdúǹbákú o bọ́ síta sọ fún akọròyìn pé irọ́ ni ìròyìn tí àwọn kan ń gbé kiri pé gbajúgbajà olórin náà ti dágbére fáyé, kí àwọn èèyàn tàkìtì ìpàkọ́ sí ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ náà.
Ṣaájú ni ìròyìn kan gbòde lórí ayélujára pé agbaọjẹ olórin juju ọ̀hún ti gbẹ́mìí mì nílé ìwòsàn kan ní ìlú Lọ́ńdọ́nù.
Ṣùgbọ́n Odunbaku sọ fún akọròyìn pé kò sí òtítọ nínú ìròyìn náà.
Ó ní “Nǹkan bíi Ìṣẹ́jú márùn ún ṣẹ̀yìn ní mo ṣẹṣẹ bá bàbá sọ̀rọ̀ lórí awuyewuye pé wọ́n papòdà, ṣùgbọ́n kò sí nǹkan kan tó ṣe bàbá, àlàáfíà ni wọ́n wà.”
Ó tẹ̀síwájú pé irọ́ ni pé Ebenezer Obey wà ní ìlú òyìnbó.
Ọdúǹbákú parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìlú Èkó ni bàbá wà lásìkò tí òun ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, àti pé kokoko lara rẹ̀ le.
Fẹ́mi Akínṣọlá