Ó dìgbà Kehinde Ayoola, Makinde, PDP, APC, ALGON ,ṣe ìdárò akọni
Bá a kú làá dère, èèyàn kò sunwọ̀n láàyè.Gómìnà Ṣèyí Mákindé ti sàpèjúwe ọ̀kan lára àwọn Kọmíṣọ́nnà rẹ̀, Kẹhinde Ayọọla tó papòdà ní Ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹrìnlá oṣù karùn ún ọdún 2020 bí ọ̀rẹ́ tòótọ síi. Kẹhinde Ayọọla ló jáde láyé lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́.
Gbínrín gbínrín ni gbogbo ọ́fíìsì kan ní ìpínlẹ̀ náà,ti nǹkan sì dákẹ́ tójú gbogbo sì fàro ni ìdárò ikú rẹ̀.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti sàpèjúwe ikú Kọmíṣọ́nnà náà bíi àjálù ńlá tó báni lójijì.
Ó ní ó jẹ́ ìbànújẹ́ ńlá fún òun nítorí pé ọrẹ ni olóògbé náà jẹ́ sí òun.
Gómìnà Mákindé ní ọdún 2002 l’òun àti olóògbé Kẹhinde Ayọọla pàdé, tí ó sì jẹ́ Olóòtọ́ àti olùfọkànṣìn èèyàn.
Gómìnà Mákindé nìkan kọ ló dárò Kọmíṣọ́nnà fọ́rọ̀ àyíká àtọ̀hún àlùmọ́ọ́nì ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ náà, Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti APC pẹ̀lú kò gbẹ́yìn.
Nínú ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn tirẹ̀, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nínú àtẹjáde kan tí wọ́n fi síta èyí tí agbẹnusọ rẹ̀, Akeem Ọlatunji fọwọ́sí sàpèjúwe Ayọọla gẹ́gẹ́ bí akínkanjú ọmọogun tó sì tún jẹ́ ẹlẹ́yinjú àánú nígbà ayé rẹ̀.
Ní tirẹ̀, ẹgbẹ́ òṣèlú APC sàpèjúwe ikú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi àjálù ńlá fún gbogbo olùgbé ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Bákan náà ni ẹgbẹ́ àwọn Alága Ìjọba ìbílẹ̀, ALGON ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pẹ̀lú sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì wòye pé, lójú tàwọn , olóògbé Kẹhinde Ayọọla nìkan làwọn rí gẹ́gẹ́ bíi ọlọpọlọ pípé tí àwọn rí tọ́kasí ní ìṣèjọba Gómìnà Ṣèyí Mákindé.
Kọmíṣọ́nnà fọ́rọ̀ àyíká àtohun àlùmọ́ọ́ní ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Kẹhinde Ayọọla dákẹ́ sí iléèwòsàn aládàáni kan lágbègbè Iyaganku ni ìlú Ìbàdàn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwé Ìròyìn abẹ́lé ṣe sọ.
Títí di bí a ṣe ń kó Ìròyìn yìí jọ, kò tíì sí ẹni leè sọ ní pàtó ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun tí a gbọ́ ni pé, òun fúnra rẹ̀ ló wa ọkọ̀ lọ sí iléèwòsàn náà ní ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn fún àyẹ̀wò ìlera rẹ̀ tí wọ́n sì dáa dúró láti sinmi. Láti ìgbà náà wá ni a gbọ́ pé ó ti wà níbẹ̀ kí ó tó dágbére fáyé lọ́jọ́bọ.
Fẹ́mi Akínṣọlá