O̩wó̩ pálábá 185 nínú o̩mo̩ e̩gbé̩ òkùnkùn ségí l’Eko
Yínká Àlàbí
Komisona olopaa ni ipinle Eko, Ogbeni Hakeem Odumosu tenu moo ipinle Eko ko ni faaye gba egbe okunkun rara.
Eyi lo faa to fi tete pakiti mole lati gbogun ti awon omo naa bi olobo se taa.
Lati ipari osu karun-un ni iroyin ti n kan ago olopaa pe awon egbe okunkun Eiye ati Aiye n gbena woju ara won.
Awon egbe yii si n fi ibon ati awon nnkan oloro miiran pa ara won paapaa ni agbegbe Ikorodu.
Ija miiran tun fe bere ni olobo ta awon olopaa ni eyi to si mu ki “owo palaba awon omo egbe marundinlaadowaa (185) segi”.
Agbegbe Shagamu,Igbogbo,Ibeshe, Ipakodo,Agbowa ati bee bee lo ni owo ti te awon omo yii ni ilu Ikorodu.
Awon egbe ti owo awon olopaa ti te awon omo won ju ni Eiye, Aiye, Kk, Buccaneers ati Vikings confraternity.
Die ninu awon Oloye egbe towo olopaa te ni Gbadamosi Mohammed, Onibudo Afeez,Habeeb Isa,Felix Igwoke, Taiwo Iyanu ati Adeoye Daya.
Awon olopaa gba ibon pisitu oyinbo mejo,ibon ibile kan pelu awon ohun ija oloro lorisiirisii.
Awon olopaa ni awon ti owo te naa ko ni pe foju ba ile-ejo.