Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ àwọn tó f’ọ́lé e MKO Abiola
À ṣẹ kò sééyan táyé ò lé bá ṣọ̀tá, ó tún hàn pé wọ́n le bínú òkú ọ̀run , yàtọ̀ sèèyan tí wọ́n jọ ń wà láyé. À bí kín ní ká tí pé tàwọn kọ̀lọ̀rànsí t’ọ́wọ́
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti tẹ̀ báyìí pé wọ́n digunjalè sọsẹ́ nílé olóògbé Olóyè Moshood Abíọ́lá tó wà ní Ìkẹjà nílùú Èkó níbi tí wọ́n ti jí nǹkan tó tó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù lọ.
Abíọ́lá ló jáwé olúborí nínú ìbò Ààrẹ gbogbogbòò tó wáyé lọ́dún 1993 èyí tí Ọ̀gágun fẹ̀yìntì Ibrahim Babangida wọ́gilé nígbà náà.
Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá nípìńlẹ̀ Èkó, Hakeem Odumosu ló sọ pé ọwọ́ àwọn agbófinró ti tẹ àwọn amòòkùnṣèkà ẹ̀dá ọ̀hún tí wọ́n yabo ilé Abíọ́lá L’ọ́jọ́rùú.
Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá tó sàbẹ̀wò sí ilé ọ̀hún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé mẹ́ta làwọn olè ọ̀hún ṣùgbọ́n ọ̀kan lára wọn ló gbé ìbọn dání.
Ọ̀gbẹ́ni Odumosu ní ”ẹbí Abíọ́lá sọ f’óun pé àwọn olè náà jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ góòlù àti owó lọ.”
”Àwọn agbófinró ti wà lojufo báyìí lágbègbè ìkẹjà tí ilé náà wà tó fi dé ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá tó wà ní ibodè Ìdírókò àti Seme,” Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá ló sọ bẹ́ẹ̀.
Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ní kò sí ẹni tó farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà nínú ìyàwó Abíọ́lá, Bísí àti ọmọbìnrin méjì tó wà nílé.
Ọ̀gbẹ́ni Odumosu fikún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìwádìí ṣì ń tẹ̀ síwájú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àwọn Aládùgbóò tó báwọn akọròyìn ṣọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé géètì tó wà lẹ́yìn làwọn olè bá wọlé, wọ́n ní láago mẹ́rin ìdájí ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé nígbà táwọn ẹṣọ tó wà nínú ilé náà ti sùn lọ.
Fẹ́mi Akínṣọlá