Buhari kí Obaseki kú oríire
Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ránṣẹ́ kú orííre sí Godwin Obaseki lẹ́yìn tó jáwé olúborí nínú ìdìbò gómìnà tó wáye lónìí nípìnlẹ̀ Edo.
Obaseki tó jẹ́ olùdíje dupò gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló fi ìdí akẹgbẹ́ rẹ̀ lábẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC Ize-Iyamu janlẹ̀.
Nínú àtẹjáde náà ti Garba Shehu tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún Ààrẹ Buhari lórí ìpolongo fọwọ́sí, ló ti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn elétò ìdìbò fún bi wọ́n ṣe kéde Obaseki bí ẹni to jáwé olúbori.
Ó fí kún-un pé èyi fi kún àrídáju pé ìjọba Ààrẹ Buhari nígbàgbọ́ nínú ètò ìdìbò tí kò ní kọ́núnkọ́họ nínú.
Bákan náà ló fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i pé, kó fi àṣeyọrí rẹ̀ hàn nínú oore ọ̀fẹ́ àti ìrẹ̀lẹ̀.
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọmọ Oòduà Naija Gist | News From Nigeria | Entertainment gist Nigeria|Networking|News.. Visit for Nigeria breaking news , Nigerian Movies , Naija music , Jobs In Nigeria , Naija News , Nollywood, Gist and more


Hope they won’t lure him back to APC