Home / Art / Àṣà Oòduà / AJE NIMO FẸẸ!

AJE NIMO FẸẸ!

.
AJE NIMO FẸẸ!
Ohun aje f’oju miri ẹnu o le sọ;
Oju miri to lori ọrọ aje;
Owo(business) f’ẹgbin rẹmi lara;
Ninu ẹgbin lọla fiṣe ile;
Ọrọ kobakungbe inu iṣẹ-aje ni ngbe.
Aje ogugu ni sọ;
Onisọ iboji o;
Aje jọwọ fi ile mi ṣe’bugbe;
Bi eṣu ọdara ṣe gbajumọ to;
Ko gbajumọ to owo;
Aje fi ile mi ṣe’bugbe o;
Ẹja o ni tobi titi;
K’omi magbe mi;
Ẹyin lọmọ adiyẹ n tọ‘ya ẹ;
Emi ni ki nmaa ran owo niṣẹ;
Aje jọwọ fi ile mi ṣe’bugbe o.
Ibi tan ti n nawo;
Jeki nba wọn naa;
Ibi tan ti n gbayi;
Ẹlẹda mi jẹ ki ntayọ(best)
Owo Dangote ko le to temi.
Agbe to ngbe ire pade olokun;
Ma gbe pade olokun mọ;
Agbe to ngbe ire pade ọlọsa;
Ma gbe pade ọlọsa mọ;
Ọdọ gbogbo eni to n ka ewi yii  ni ki ogbe lò
Ọmọ Ajifọlajifaọla ni won ku se
Gbogbo Wa Lao Ri T’owo Ṣe O. Ao Ni Wa Owo Ti Laṣẹ Ọlọrun
Amin.
*OJUMO’RE*

About Awoyemi Bamimore

Viral Video

Support Ooduarere

SUPPORT OODUARERE
Scan QR code below to Donate Bitcoin to Ooduarere
Bitcoin address:
1FN2hvx5tGG7PisyzzDoypdX37TeWa9uwb
x

Check Also

Free Dele Farotimi | Seun Kuti