Óríre míràn ti to omo kékeré, omo odún mókànlá tí a mò sí Kareem Waris Olamilekan tí olórun fún ní èbùn kí ó ma ta nkan, ó ti ya ààre ilè Faransé tí a mò sí Ààre Emmanuel Macron, nígbà tí ó lo se àbèwò sí ojúbo Afrika tuntun ní ìlú Èkó.
Léyìn tí ó gba ilé ní owó Gómìnà ìpínlè Eko, ilé-ìfowópamó tí a mò sí Eko bank, ti towó bo ìwé láti gbà á tó lówó àwon òbí rè. Lára àwon èjé won ni wípé àwon yòó tó omo náà àti wípé àwon yóò ran lo sí ilé-èkó fún ogún odún(20 years).
Nínú ìfòrò wáni lénu wò tí won se fún alákoso Kareem tí a mò sí Adeniyi Adewole, ó jé kí ó di mímò wípé gbogbo ònà ni àwon n wá láti dábò bo ojó òla ayàwòrán omodé náà .
Ó so wípé inú òun dún púpò nítorí ilé-ìfówópamó ti Eco bank látàrí èjé tí won jé láti tójú omo náà. Ó so síwájú wípé sojú òun ni won se nígbá tí ó jé wípé òun ni Alákoso omo náà àti wípé won kò le se léyìn òun.