Buhari bá ìpínlè̩ Eko ké̩dùn – Ìròyìn lati o̩wó̩ Yínká Àlàbí
Ojo buruku esu gbomi mu ni ojo isinmi oni je fun awon ara agbegbe Amuwo Odofin ni adugbo FESTAC.
Ijamba ina naa bere ni aago mesan-an aaro. Opa epo ni won lo dede bu gbamu ti ina so.
Ina naa ti mu emi ti ko din ni mejidinlogun lo.
Opo dukia ti ko niye lo ti ba isele buruku naa lo.
Aare Mohammadu Buhari naa ranse ibanikedun si ijoba ipinle Eko. O si ba gbogbo ebi to padanu eniyan won kedun.
Komisona olopaa ni ipinle Eko, Ogbeni Akeem Odumosu ni ijamba ina naa sele latiari moto akoyepe nla kan to fagidi koja ni adugbo naa. O ni kii se awon to n doju ija ko ilu bii boko haram lo dana si opa epo naa gege bi awon kan se n gbee pori enu lori ero ayelujara.
Ki Eledua ma se je ki a ri iru re mo.